Atiku ko ni anfaani kan ṣoṣo to fẹẹ ṣe fun Naijiria, Tinubu nikan ni ko le ṣe ijọba ẹlẹyamẹya - Alaaji Maigogo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, January 20, 2023

Atiku ko ni anfaani kan ṣoṣo to fẹẹ ṣe fun Naijiria, Tinubu nikan ni ko le ṣe ijọba ẹlẹyamẹya - Alaaji Maigogo


Alakoso igbimọ olupolongo fun ipo Aarẹ ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, iyẹn 'The Committee Support Directorate for Bola Ahmed Tinubu for President and Kashim Shettima as Vice President', Alaaji A. A. Maigogo ti sọ pe oludije sipo Aarẹ lẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Alaaji Atiku Abubakar ko ni anfaani rere to fẹẹ ṣe fawọn ọmọ orileede Naijiria.

O ni Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu ati igbakeji re nikan lo ni ipiinu rere fun awọn ọmọ Naijiria, ti yoo si mu orileede yii de ilẹ ileri, lẹyin to ba de ori ipo Aarẹ lọdun ti a wa yii.

Alaaji Maigogo lo sọrọ naa niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun l'Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii lakoko to n fi igbimọ olupolongo, ẹka ti ilẹ Yoruba lelẹ, to si tun bura fun awọn ti wọn ṣẹṣẹ yan.

Nibẹ lo ti gba gbogbo awọn igbimọ tuntun naa lamọran lati lo ipo wọn lati tubọ maa fi polongo fun awọn ti wọn n ṣoju fun, ki ohun ti wọn n fẹ le tẹ wọn lọwọ.

Lara awọn to wa nibẹ ni awọn ọmọ ẹgbẹ lati ipinlẹ Ogun, Ọyọ ati Ekoo, ti Alaaji Maigogo si jẹ ko di mimọ pe wọn yoo fi awọn igun keji lati Ọṣun, Ekiti ati Ondo lelẹ laipẹ

Nigba to n sọrọ lẹyin ibura naa, Alaaji Maigogo ṣalaye pe Tinubu ati Shettima nikan ni wọn kaju oṣuwọn laaarin awọn oludije to farahan fun ipo Aarẹ, nitori pe o jẹ olotitọ eeyan, kii ṣe alagabagebe, bẹẹ si ni kii ṣe adari ẹlẹyamẹya.

Bakan naa lo sọ pe igbakeji rẹ, Shettima naa ti ṣe awọn ohun to dara gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Borno lẹẹji ọtọọtọ.

O ni Atiku lo ye ki koun tẹlẹ nitori pe awọn jọ wa lati ẹya kan naa ni, ṣugbọn nitori pe oun mọ iru eeyan to jẹ, ti ko si ni anfaani rere kan to fẹẹ ṣe fun Naijiria ni ko jẹ koun le tẹle.

"Bi mo ba fẹẹ ṣe ojusaaju, maa ti ba Alaaji Atiku Abubakar lọ fun ipo Aarẹ, nitori pe Fulani kan naa la jọ jẹ, ṣugbọn ko ni anfaani rere kan to fẹẹ ṣe fun orileede yii, idi ree ti mo fi tẹle ẹnikan ṣoṣo to kaju oṣuwọn julọ, to si maa ṣe daadaa, Aṣiwaju Tinubu."

Ninu ọrọ tiẹ naa, Ọnarebu Adewale Adeogun to jẹ alakoso nipinlẹ Ogun rọ gbogbo awọn ọmọ igbimọ lati maa polongo awọn oludije wọn lojoojumọ, titi ti ipo ọhun yoo fi ja mọ wọn lọwọ.

O ni bi wọn ṣe n polongo fun ọmọde naa ni ki wọn maa polongo fun agbalagba, onile ati alejo, ki wọn le ri ibo to pọ fawọn ti wọn n ṣoju.

Bẹẹ lo gba gbogbo awọn oludibo lati tete lọ gba kaadi idibo alalopẹ wọn ki asiko too lọ lọdọ ajọ eleto idibo, iyẹn INEC, eyi ti yoo fun wọn lanfaani lati dibo ninu oṣu keji ati oṣu kẹta ọdun yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI