Ko tii sẹni to le sọ pato ohun to ṣẹlẹ lori bi iyaale ile kan ati ọmọ rẹ ṣe pokunso lọjọ kan ṣoṣo, eyi to ko iyalẹnu ba pupọ awọn eeyan.
Agbegbe Ajoa to wa ni Ahanta West Municipality, Western Region, orileede Ghana ni iṣẹlẹ ọhun ti waye laaarọ Ọjọru, Wẹsidee ọsẹ yii, iyẹn ọjọ kejidinlogun, oṣu kinni ọdun ti a wa yii.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni obinrin naa ti koko ki okun bọ ọmọ rẹ lọrun, to si gbe e kọ. Lẹyin eyi ni wọn loun naa pokunso.
Wọn ni gbogbo asiko ti obinrin naa n ki okun bọ ọmọ rẹ ọhun lọrun, lọmọ naa n sunkun rẹpẹtẹ, ṣugbọn ti awọn eeyan ko mọ ohun to n ṣẹlẹ.
Ọkan lara awọn ara adugbo, Nana Yaw to sọrọ ṣalaye pe;
“A wa ṣiṣẹ gẹgẹ bi oṣiṣẹ nile akọku yii ni, igba ti a de la ri oku obinrin yii ati ọmọ rẹ, nibi ti wọn pokunso si.
“Obinrin naa ko tii le ju ogun ọdun si ọdun mẹtalelogun lọ, nigba ti ọmọ rẹ naa ko tii ju ọmọ ọdun mẹrin lọ. A ko mọ ibi ti wọn ti wa, bẹẹ si la ko mọ mọlẹbi wọn kankan. Bi ẹ ba wo o, wọn ko tii tu okun ọrun wọn silẹ.”
Ọmọ ile igbimọ aṣofin to n ṣoju agbegbe Ajoa naa, Robert James Yankey naa fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, to si lo ya oun lẹnu pupọ.
“Gẹgẹ bi awọn ohun ti mo ti gbọ, wọn l'awọn kan ṣi ri obinrin naa nnkan bi aago mẹrin irọlẹ, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee to n tọrọ owo fun ọmọ rẹ. Ko tun s'ẹni to ri wọn mọ yatọ si oku wọn ti wọn pada ri ninu ile akọku.
"A ko mọ obinrin naa ri lagbegbe wa yii, igbagbọ wa ni pe ibomiran lo ti wa.”
No comments:
Post a Comment