Banki apapọ (CBN) fọjọ mẹwaa kun gbedeke ọjọ ti wọn yoo na owo naira atijọ ni Naijiria - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, January 29, 2023

Banki apapọ (CBN) fọjọ mẹwaa kun gbedeke ọjọ ti wọn yoo na owo naira atijọ ni Naijiria


Banki agba orileede Naijiria, Central Bank of Nigeria
(CBN) ti sọ pe awọn ti fi ọjọ mẹwaa kun gbedeke ọjọ ti awọn ọmọ orileede yii yoo na owo naira atijọ.
 
Afikun naa ni CBN sọ pe awọn fẹẹ jẹ ki owo tuntun yika gbogbo orileede yii, ki awọn eeyan si lanfaani lati lọ sẹ paṣipaarọ owo atijọ si tuntun.
 
Ọjọ kẹwaa, oṣu keji, ọdun 2023 ni CBN sọ pe nina owo atijọ igba naira, ẹẹdẹgbẹta naira ati ẹgbẹrun kan naira yoo dopin kaakiri Naijiria.
 
Ninu atẹjade ti CBN gbe jade lonii, ọjọ Aiku, Sannde, ni wọn ti fidi rẹ mulẹ pe ki awọn eeyan fọkanbalẹ lati lọ paarọ owo naa.
 
Bẹ o ba gbagbe, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kinni, ọdun ti a wa yii ni CBN ti kọkọ kede gbedeke ninu owo atijọ naa.
 
Godwin Emefiele tun fi kun ọrọ rẹ pe yatọ si pe ọjọ kẹwaa, oṣu keji ni yoo jẹ gbedeke nina owo naa, o ni oore ọfẹ tun ṣi wa titi di ọjọ kẹtadinlogun, oṣu keji, ọdun yii fun awọn to ba fẹẹ ṣe paṣipaarọ owo atijọ si tuntun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI