Ìdájọ ìgbẹ̀yìn láti yọ Buhari n'ípò gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Nàìjíríà yóò wáyé lọ́jọ́ Ajé, Mọ́ndè ọ̀la - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, January 29, 2023

Ìdájọ ìgbẹ̀yìn láti yọ Buhari n'ípò gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Nàìjíríà yóò wáyé lọ́jọ́ Ajé, Mọ́ndè ọ̀la


Ile ẹjọ giga to wa niluu Abuja, olu-ilu orileede Naijiria yoo gbe idajọ nla kalẹ, eyi ti wọn fi n pe fun yiyọ Aarẹ Muhammadu Buhari n'ipo gẹgẹ bi Aarẹ Naijiria.

Ẹsun ṣiṣe magomago ninu eto idibo ọdun 2019 to kọja lọ ni wọn fi kan Aarẹ Buhari, ti idajọ to gbẹyin yoo si waye lọjọ Aje, Mọnde, ọgbọn ọjọ, oṣu kinni, ọdun 2023 ti a wa yii.

Onidajọ Inyang Ekwo la gbọ pe yoo gbe idajọ naa kalẹ, leyi ti yoo tun maa ṣagbeyẹwo dida eto idibo to fẹẹ waye lọjọ karundinlọgbọn, oṣu keji duro.

Aago mẹsan ni Onidajọ Ekwo yoo bẹrẹ igbẹjọ ọhun, iwe naa ti awọn akọroyin ṣalabapade rẹ lọjọ Ẹti, Furaidee to kọja nileeṣẹ eto idajọ orileede yii niluu Abuja.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe mimisita f'ọrọ eto idajọ lorileede yii, Abubakar Malami ni wọn fi iwe naa ranṣẹ si, lati fi too leti, gẹgẹ bi olori amofin ni Naijiria.

Oludije sipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Hope Democratic Party, Oloye Ambrose Owuru to jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Rivers lo wọ Aarẹ Buhari ati ajọ eleto idibo, iyẹn INEC lọ sile ẹjọ, nibi to ti sọ pe iwa magomago wa ninu eto idibo ọdun 2019.

Owuru, ẹni to kẹkọọ ijinlẹ nipa iṣẹ ofin nilẹ Biritiko lo n rawọ ẹbẹ si ile ẹjọ giga lati kede oun gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu eto idibo ọdun naa.

Bakan naa lo tun n rọ ile ẹjọ lati ṣagbeyẹwo idi ti ajọ INEC ṣe sun eto idibo to yẹ ko waye lọjọ kẹrindilogun siwaju si ọjọ kẹtalelogun.

O ni igbese ti ajọ INEC gbe ko ba ofin mu, nipa bi wọn ṣe sun idibo Aarẹ siwaju, to si ni ki wọn wọgile bi wọn ṣe kede Muhammadu Buhari gẹgẹ bi aarẹ.

Siwaju sii lo ni ki ile ẹjọ naa kede oun gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori, ki wọn si paṣẹ fun Aarẹ Muhammadu Buhari lati da gbogbo owo to ti gba laaarin akoko to fi wa lori ipo saa keji pada lai fi akoko ṣofo.

Onidajọ Ekwo lo buwọ lu ọgbọn ọjọ, oṣu yii gẹgẹ bi ọjọ ti idajọ igbẹyin yoo waye, lẹyin ti Aarẹ Buhari, minisita f'ọrọ eto idajọ ati ajọ INEC ti panupọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI