Bi mo ba fẹẹ pada s'ipo aarẹ lẹẹkẹta, ko sẹni to le da mi duro - Ọbasanjọ tun sọrọ lori awuyewuye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, January 13, 2023

Bi mo ba fẹẹ pada s'ipo aarẹ lẹẹkẹta, ko sẹni to le da mi duro - Ọbasanjọ tun sọrọ lori awuyewuye


Aarẹ tẹlẹri lorileede Naijiria, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti sọ pe ko si ohun to jọ ọ wi pe oun fẹẹ pada s'ipo aarẹ lẹẹkẹta, iyẹn lakoko toun wa n'ipo naa lọdun bii meloo sẹyin.
 
Ọbasanjọ ni awuyewuye ti ko si otitọ ninu rẹ rara ni wi pe boya oun tun fẹẹ ṣe aarẹ Naijiria lẹẹkẹta, o lawọn to n gbe iroyin naa kaakiri kan n sọ ohun to wu wọn lasan ni.
 
Ẹbọra Owu lo sọrọ naa nibi itakurọsọ ẹgbẹ awọn adari ilẹ Afrika, eyi ti Pasitọ Itua Ighodalo tukọ rẹ lori ikanni ayelujara ti a mọ si Virtual.
 
Itakurọsọ naa ti wọn pe akori rẹ ni "Adari ati gbigbe orileede dagba" - (Leadership and nation-building). ni Ọbasanjọ ti jẹ ko di mimọ pe oun ko beere fun saa kẹta n'ipo toun wa n'ipo aarẹ.

"Mi o figba kan beere fun saa kẹta, Bi mo ba fẹẹ ṣe ẹlẹẹkẹta, maa ti ṣe e. Mo ni agbara lati mọ bi maa ṣe gba saa kẹta."
 
Nibẹ naa lo tun ti sọ pe pipa gbese rẹ fun orileede jẹ ohun kan pato to ṣoro, ṣugbọn o jẹ aṣeyọri fun mi wi pe oun le ṣe e.
 
O wa jẹ ko di mimọ pe iṣoro nla kan ṣoṣo ti ilẹ Afrika ni lonii ni adari.
 
"Naijiria wa nibi ti wọn wa lonii nitori adari wọn. A ni lati fi oju silẹ daadaa lati yan awọn ọkunrin ati awọn obinrin ti wọn ni iwa, iṣesi, ọkan akikanji ati itara ti a nilo fun ipo adari lati gba orileede yii silẹ."
 
Siwaju sii nigba ti wọn n beere lọwọ rẹ boya yoo gbe awọn eeyan dide lati polongo ibo fun Peter Obi, oludije s'ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Labour, Ọbasanjọ sọ pe ko si ohun to jọ ọ.
 
"Mi o si ninu ọkọ olupolongo rẹ. Mi o si nii darapọ mọ ikọ olupolongo kankan. Mo ti sọ awọn ohun to yẹ fun orileede yii."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI