Pasitọ to ji ara rẹ gbe lẹẹmeji ti sọrọ, o ni 'mo broke' ni - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, January 13, 2023

Pasitọ to ji ara rẹ gbe lẹẹmeji ti sọrọ, o ni 'mo broke' ni


Pasitọ kan ti iroyin gbe jade laipẹ yii wi pe o ji ara rẹ gbe lẹẹmeji ọtọọtọ ti sọ pe nitori owo ti ko si lọwọ oun, loun ṣe pinnu lati ji ara oun gbe, toun si gba owo lọwọ awọn ọmọ ijọ oun.
 
Albarka Bitrus Sukunya lorukọ rẹ, wọn si loun lo n dari ẹka ṣọọṣi ECWA to wa niluu Jos, ipinlẹ Plateau.
 
Ọjọ kọkanla, oṣu kinni ọdun yii, iyẹn Ọjọru, Wẹsidee to kọja lọwọ tẹ Sukunya, ko to di pe wọn f'oju rẹ han f'awọn akọroyin l'Ọjọbọ, Tọsidee, ana.
 
Nigba to n sọrọ, o ni
"Mo gbe ara mi sinu iṣẹ yii nitori ipenija aisi owo ti mo n koju. Nigba ti mo ṣe akọkọ, ẹri ọkan jẹ mi. Nigba ti mo jade, owo naa tun ti tan. Mo wa n ronu bi mo tun ṣe le pada si iṣẹ naa.
 
"Idi ree ti mo fi pada si i. Ṣugbọn ṣa, mo kabamọ wi pe mo ji ara mi gbe, ti mo si gba owo lọwọ awọn ọmọ ijọ mi."
 
Siwaju sii la tun gbọ pe Sukunya tun dana sun mọto ọkan lara awọn ọmọ ijọ rẹ.
 
"Mo dana mọto naa, nitori pe ẹri ọkan jẹ mi fun iwa ti mo hu. Ọkan mi kan n poruru ni. Mi o mọ ohun to bale mi. Nitori mo jẹ pasitọ, idi niyẹn ti ẹmi Ọlọrun ko ṣe faaye gba mi lati lọ lai jẹwọ ohun ti mo ti ṣe. Ẹ ma binu f'oun ti mo ṣe, ẹ fori jin mi."
 
AWIKONKO gbọ pe ẹgbẹrun lọna irinwo naira ni Sukunya gba nigba to ji ara rẹ gbe lọjọ kẹrinla, oṣu kọkanla, ọdun 2022, bẹẹ naa lo tun gba ẹgbẹrun lọna igba naira nigba to tun ji ara rẹ gbe lọgbọn ọjọ, oṣu kọkanla, ọdun 2022.

1 comment:

  1. Olorun yio gbawa lowo awon ayederu iranse olorun

    ReplyDelete

PÍN-IN KÁÀKIRI