Igbakeji oludije sipo Aarẹ Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu, iyẹn Kashim Shettima ti sọ pe gomina ana nipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayọṣe gba oun tọwọtẹsẹ.
Kashim Shettima lo sọrọ naa loju opo Fesibuuku rẹ lonii, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to si loun dupẹ gidigidi lọwọ Fayọṣe.
Ninu ọrọ to kọ, o sọ pe;
Mo ṣe abẹwo si Arakunrin mi, gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ọlọlajulọ Ayọdele Peter Fayọṣe
Oṣhoko gba wa lalejo pẹlu ikinikaabọ nla, ifẹ ati ọyaya. O ṣeun fun aduroti, ifọwọsowọpọ, Ọlọrun a si bukun fun ẹ fun boo ṣe gba emi ati ikọ akọwọrin mi lalejo.
No comments:
Post a Comment