O ma ṣe o: Wọn dumbu ọmọ ọdun mejila bi ẹran nibi to ti lọ gba foonu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, January 25, 2023

O ma ṣe o: Wọn dumbu ọmọ ọdun mejila bi ẹran nibi to ti lọ gba foonu


Ọmọ ọdun mejila kan, Abdulkadir la gbọ pe wọn ti dumbu bi ẹran lasiko to lọ gba foonu lọdọ ẹni to oba wọn fi ina sara foonu.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii ni iroyin fi to wa leti pe wọn pa ọmọdekunrin naa danu.
 
Agbegbe ti wọn pe ni Madarkaci, ipinlẹ Zaria ni wọn sọ pe Abdulkadir n gbe.
 
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe irọlẹ ọjọ Aiku, Sannde ni wọn ran ọmọ naa niṣẹ lati lọ gba foonu wa, ṣugbọn ti ko pada sile. Nigba ti wọn yoo pada ri, oku rẹ ni wọn ri, ti wọn ti dumbu ẹ.

Nigba to n sọrọ, baba ọmọ naa, Aminu Saleh Muhammad ṣalaye pe inu ile akọku kan  ni wọn ti pada ṣalabapade oku ẹ
 
Mohammed sọ pe bawọn ṣe ri iku ọmọ naa, o jọ pe awọn oloogun owo ni wọn pa oun lọmọ, nitori pe niṣe ni wọn yọ oju, nnkan ọmọkunrin ati ahọn rẹ lọ.
 
Yatọ si eyi, baba naa tun sọ pe wọn kan ọmọ oun lẹsẹ ti wọn si tun fọ ori ẹ danu ko too ku.
 
O wa rawọ ẹbẹ sawọn ọlọpaa lati gbe oku ọmọ oun silẹ lati lọ sin in nilana musulumi.
 
Agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa, DSP Muhammad Jalige ninu ọrọ rẹ sọ pe bo tilẹ jẹ pe iwadii ṣi n lọ lọwọ lati mu awọn amookunṣeka naa, sibẹ o ni iwa ọdaju ni wọn hu naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI