Ẹ di ile mu o, mo ti lọ Sẹnẹgal lo b'awọn ṣepade o - Buhari sọ f'awọn ọmọ Naijiria - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, January 24, 2023

Ẹ di ile mu o, mo ti lọ Sẹnẹgal lo b'awọn ṣepade o - Buhari sọ f'awọn ọmọ Naijiria


Aarẹ Muhammadu Buhari ti orileede Naijiria ti dagbere fun gbogbo araalu, to si jẹ ko di mimọ pe orileede Sẹnẹgal loun lọ lati bawọn kopa nibi ipade gbogboogbo to nii ṣe pẹlu eto agbẹ ati ọgbin, iyẹn
Dakar International Conference on Agriculture, ẹlẹẹkeji iru ẹ.

Oni, ọjọ Iṣẹgun, Tuside, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kinni, ọdun 2023 ni Aarẹ Buhari gbera lati papakọ ofurufu ti Murtala Muhammed to wa ni Ikẹja l'Ekoo.
 
Gẹgẹ bi atẹjade ti oludamọran pataki fun Aarẹ lori ọrọ iroyin, Ọgbẹni Fẹmi Adeṣina fi sita ṣe sọ, o ni niṣe ni wọn fi iwe pe Aarẹ Buhari sibi eto naa.
 
Adeṣina jẹ ko di mimọ pe Aarẹ ilẹ Sẹnẹgal, Macky Sall, ẹni to tun jẹ alaga ẹgbẹ awọn agba ilẹ Afrika lo gbe eto naa kalẹ, eyi to pe akori t'ọdun yii ni “Feeding Africa: Food Sovereignty and Resilience.”
 
O ni orileede Sẹnẹgal pẹlu banki idagbasoke ilẹ Afrika, iyẹn African Development Bank lo ṣagbatẹru eto naa nipa iwe adehun, pẹlu erongba lati wa ọna ti aabo yoo fi wa fun ounjẹ nilẹ Afrika.
 
Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ pe awọon alẹnulọrọ ninu ijọba bii minisita fọrọ ilẹ okeere, Geoffrey Onyeama; Minisita fọrọ iṣẹ agbẹ ati idagbasoke igberiko, Ọmọwe Mohammad Mahmood Abubakar; Oludamọran agba pataki lori ọrọ eto aabo, Mohammed Babagana Monguno ati alakoso agba fun ajọ National Intelligence Agency (NIA), Ambassador Ahmed Rufai Abubakar ni yoo kọwọrin pẹlu Aarẹ lọ sibẹ.
 
Siwaju sii lo sọ pe Aarẹ ko nii pẹ nibẹ rara, nitori pe Ọjọru, Wẹsidee, ọjọ karundinlọgbọn ni yoo pada si Naijiria.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI