Ẹ wa gbọ ẹkunrẹrẹ alaye bi akẹkọọ FUTA ṣe pokunso - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, January 24, 2023

Ẹ wa gbọ ẹkunrẹrẹ alaye bi akẹkọọ FUTA ṣe pokunso



Akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ fásitì nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ ti ìjọba àpapọ̀ tó wà ní ìlú Akure, FUTA, Olona Babajide Joseph, ti gba ẹ̀mí lọ́rùn ara rẹ̀. 
 
Òkú Olona ni wọ́n bá nínú ilé rẹ̀ tó wà ní agbègbè Aule, Akure, olú ìlú ìpínlẹ̀ Ondo níbi tó pokùn so sí. 
 
Olóògbé náà tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Black, ló jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ onípele kẹta lẹ́ka ìmọ̀ Industrial Design ní ilé ẹ̀kọ́ gíga FUTA. 
 
Ohun tó ṣokùnfà ìdí tí Olona fi pokùn so ní a ò tíì le fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ní pàtó. 
 
Àmọ́ ọ̀rẹ́ Olona kan, Omoniyi Enoch tó bá àwọn akọ̀ròyìn ilé ẹ̀kọ́ náà sọ̀rọ̀ ní ó ṣeéṣe kó jẹ́ wí pé nítorí ẹ̀sùn nípa owó kan, ló fà á tí Olona fi gba ẹ̀mí ara rẹ̀. 
 
Ní ojú òpó Facebook Union Campus Journalists, UCJ FUTA, ni wọ́n fi ìròyìn náà sí. 
 
Ọ̀rẹ́ olóògbé ṣàlàyé bí owó ‘department’ ṣe di gbèsè sí Olona lọ́rùn 
 
Enoch ṣàlàyé pé nígbà tí àwọn padà sẹnú ètò ẹ̀kọ́ fún sáà 2021/2022, kò sí akápò ẹgbẹ́ ní ẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́ àwọn nílé. 
 
O ní ìdí rèé tí wọ́n ṣe yan Olona, tó jẹ́ akọ̀wé owó, láti gba owó tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa ń san sápò ẹ̀ka ẹ̀kọ́ wọn. 
 
Enoch ní nígbà tó yá, Ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní kí Olona san ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún náírà (N100,000) nínú owó tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà dá si lọ́wọ́, láti fi ṣe àkànṣe iṣẹ́ kan. 
 
“Olona lo áàpù ilé ìfowópamọ́ ìgbàlódé kan – Carbon, láti fowó náà ránṣẹ́ sí ààrẹ, owó náà kúrò ní akoto owó Olona ṣùgbọ́n ààrẹ ní òun kò rí owó.” 
 
“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àtẹ̀jíṣẹ́ ló kọ sí ilé ìfowópamọ́ yìí kí wọ́n le dá owó náà padà àmọ́ ilé ìfowópamọ́ náà kọ̀ láti dá owó ọ̀hún padà. 
 
Àsìkò yìí ni gbogbo ènìyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí ní bu Olona pé ó kó owó jẹ ni.” 
 
Enoch fi kun pé ìdí nìyí tí Olona kò fi tíì lọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ láti ìgbà tí àwọn wọlé ẹ̀kọ́ padà lẹ́yìn họlidé ọdún kérésìmesì. 
 
Ó ní èyí kò sì sẹ̀yìn bí gbogbo wọ́n ṣe ń fún ogun mọ́ ọ láti san owó náà padà. 
 
Ó tẹ̀síwájú pé ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ẹtì ni òun lọ gba fóònù òun lọ́wọ́ Olona nítorí fóònù ti Olona ń lò ti bàjẹ́, tó sì jẹ́ wí pé fóònù ti tòun ni àwọn ń pín lò. 
 
"Olona fẹ́ tẹ̀lé mi lọ sí ọ́fíìsì mi ní SUB torí kò fẹ́ dá dúró sílé àmọ́ mo fi kalẹ̀ sínú ọ́fíìsì mi ni" 
 
Ó ní ìgbà tí òun dé ọ̀dọ̀ Olona ló sọ fún òun pé HOD àwọn pe bàbá òun láti fẹjọ́ sùn pé òun kó owó jẹ. 
 
Ó ṣàlàyé pé ọ̀rọ̀ náà dùn-ún gidigidi, tó sì tún da omi tútù si lọ́kàn. 
 
“Ó ní òun máa tẹ̀lé mi lọ sí ọ́fíìsì mi ní SUB nítorí òun kò fẹ́ dá dúró sílé àmọ́ mo fi kalẹ̀ sínú ọ́fíìsì náà láti lọ kópa níbi àwọn ayẹyẹ kan.” 
 
“Kí n tó dé ló ti tilẹ̀kùn ọ́fíìsì ṣùgbọ́n nígbà tí mo dé, ló wá fún mi ní kọ́kọ́rọ́ tó sì padà lọ sílé.” 
 
“Nígbà tí mo délé mo lọ wò ó ní yàrá rẹ̀ ní nǹkan bí i aago mẹ́jọ ku ogún ìṣẹ́jú ṣùgbọ́n kò jáde sími. 
 
Mo tún padà lọ ní nǹkan bíi aago mẹ́jọ ààbọ̀ àti aago mẹ́wàá alẹ́ síbẹ̀ náà kò dáhùn, mo tilẹ̀ rò bóyá ó ń bínú pé mo fi òun sílẹ̀ lọ síbi ayẹyẹ tí mo lọ ni.” 
 
Enoch ní àárọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta ni òun padà sí yàrá rẹ̀ láti lọ kan ilẹ̀kùn ṣùgbọ́n nígbà tí kò dá òun lóhùn ni òun lọ yọjú láti ojú wíńdò, tí òun sì ri tó ti pokùn so.
  
Lóòótọ́ ni Olona kó owó department jẹ àmọ́ èyí kò tó kó para rẹ̀  - ààrẹ ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ 
 
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀, ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Industrial Design, Owomoyela Oladotun ní lóòótọ́ ni Olona Joseph ṣe owó ẹgbẹ́ kúmọkùmọ àmọ́ òun kò rò wí pé nítorí rẹ̀ ló ṣe pa ara rẹ̀. 
 
Oladotun ní àwọn ti ní àjọsọ pẹ̀lú Olona nígbà tí àwọn parí ìdánwò simẹ́sítà àkọ́kọ́ ìyẹn ní ọdún tó kọjá pé Olona máa san owó náà díẹ̀díẹ̀ títí tó ma fi san tán. 
 
Ó ní láti ìgbà náà ni òun kò ti rí Olona mọ́ àfi bí òun ṣe gbọ́ wí pé ó pokùn so. 
 
Ó kẹ́dùn pé òun tó bá òun lọ́kàn jẹ́ gidi ni nítorí owó náà kò tó òun tó yẹ kó pa ara rẹ̀ lórí. 
 
Àtẹ̀jáde kan tí ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ FUTA, Jesunifemi TenTen Asoore àti agbẹnusọ ẹgbẹ́ Adedokun Daniel Tolulope fi léde, ní ó jẹ́ ohun ìbànújẹ́ fún àwọn pé àwọn pàdánù Olona Joseph. 
 
Wọ́n wá bá àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ Olona kẹ́dùn, tí wọ́n sì tún pàrọwà sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó bá ń kojú ohunkóhun láti fi tó àwọn létí dípò gbígba ẹ̀mí ara ẹni.
 
Lati BBC YORUBA

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI