Ẹ fura o! 'Emilokan' ti Tinubu n pariwo, kii ṣe ọrọ ẹnu lasan o - Wolii Ayọdele pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, January 31, 2023

Ẹ fura o! 'Emilokan' ti Tinubu n pariwo, kii ṣe ọrọ ẹnu lasan o - Wolii Ayọdele pariwo sita


Gbajugbaja ojiṣẹ Ọlọrun nni, Wolii Elijah Ayọdele ti pariwo sita wi pe k'awọn ọmọ Naijiria tete wa ni ifura, lori ọrọ 'Emilokan' ti oludije s'ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu n pariwo lasiko yii.

Wolii Elijah Ayọdele to jẹ alaṣẹ ati oludasilẹ ijọ INRI Evangelical Spiritual Church, lo sọrọ naa ninu atẹjade ti amugbalẹgbẹ ẹ lori ọrọ iroyin, Ọgbẹni Oluwatosin ọṣhọ gbe jade l'ọsan oni, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee.
 
O ni ọrọ 'Emilokan' ti Tinubu n pa lasiko yii ni nnkan ṣe pẹlu ẹmi, to si lawọn eeyan ko fura nipa ẹ.
 
Agba Wolii alasọtẹlẹ naa ni ọrọ naa kii ṣe ohun t'awọn eeyan gbọdọ maa sọ, nitori pe ni nnkan ṣe pẹlu ipo aarẹ ti Tinubu n le ni tipatipa.
 
“Ẹ ma ṣe fi ọrọ anfaani ti APC ni ṣere, ko dagba to ninu oṣelu, o si n fẹ ipo aarẹ.
 
“Awọn ọrọ rẹ ni nnkan ṣe pẹlu ẹmi ju ọrọ ẹnu lasan lọ. Ọrọ naa kii ṣe lasan. Niṣe lo n sọrọ pẹlu aṣẹ. Ọrọ rẹ, ti ẹmi ni, ṣugbọn awọn ọmọ Naijiria ro pe ere lasan lo n ṣe.
 
“Ọrọ ‘Emilokan’ naa ni nnkan ṣe pẹlu ẹmi. ‘Emilokan’ ni lati ji ẹgbẹ oṣelu PDP ati Labour dide kuro loju oorun wọn. Ọrọ naa kọja ọrọ ẹnu lasan. Bi ẹ ko ba fẹ ki Tinubu jawe olubori, ẹni lati kọlu ọrọ ‘Emilokan.
 
“Ẹgbẹ oṣelu PDP ati Labour ni lati ṣe iwadii itumọ Emilokan ninu ẹmi, ọrọ adiitu ni ọrọ t'awọn ọmọ Naijiria fi n ṣere, kii ṣe ọrọ ere, ọrọ owe ni.
 
“Tinubu tiẹ tun le maa fi ṣere, awọn ti wọn ni oju ẹmi ni wọn le mọ itumọ ọrọ Emilokan naa.”

1 comment:

  1. Oladeji Rasheed GidadoFebruary 2, 2023 at 3:57 PM

    Woli eke to le da ilu ru ni woli na. Iru won lol ma nda rugudu sile

    ReplyDelete

PÍN-IN KÁÀKIRI