Angẹẹli iranlọwọ ni AbdulRazaq jẹ ni Kwara, ko fi owo oṣu jẹ wa niya - Ẹgbẹ awọn olukọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, January 31, 2023

Angẹẹli iranlọwọ ni AbdulRazaq jẹ ni Kwara, ko fi owo oṣu jẹ wa niya - Ẹgbẹ awọn olukọ


Ẹgbẹ awọn olukọ nipinlẹ Kwara, Nigerian Union of Teachers (NUT) ti gbe oṣuba kare fun gomina wọn, AbdulRahman AbdulRazaq lori bo ṣe sa owo oṣu ajẹẹlẹ ti awọn iṣakoso to ti kọja lọ ti jẹ awọn olukọ to wa labẹ ajọ SUBEB.

Wọn ni iwuri nla ni owo oṣu ajẹẹlẹ t'ijọba san fun jẹ, to si ni gomina to nifẹẹ araalu, paapaa awọn oṣiṣẹ ni AbdulRazaq jẹ, ati pe angẹẹli ti Ọlọrun ran si wọn ni.

Ninu atẹjade ti ẹgbẹ naa gbe sita lati ọwọ alaga wọn, Kọmureedi Oyewọ Bashir gbe jade, lo ti fidi rẹ mulẹ pe Gomina AbdulRazaq ko jẹ awọn lowo oṣu, paapaa latigba ti ẹkunwo ti ba owo oṣu, iyẹn ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira.

O wa fọkan gomina naa balẹ wi pe awọn yoo fọwọsowọpọ pẹlu ẹ lori ipinnu ati erongba rere to ni fun eto ẹkọ nipinlẹ naa.

Bẹẹ lo tun sọ pe awọn yoo dibo fun un ninu eto idibo to n bọ lọna yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI