Ẹ lọ fọkanbalẹ, ẹgbẹ oṣelu PDP maa gbe ipinlẹ Ogun dide kuro ni ipo dakudaji to wa - Aderinokun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, January 30, 2023

Ẹ lọ fọkanbalẹ, ẹgbẹ oṣelu PDP maa gbe ipinlẹ Ogun dide kuro ni ipo dakudaji to wa - Aderinokun


Olumide David Aderinokun, oludije sipo aṣofin agba lorileede Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP nipinlẹ Ogun ti parọwa s'awọn araalu lati lọ fọkan balẹ, nitori pe ẹgbẹ naa yoo gbe ipinlẹ ọhun dide pada.

Aderinokun, ẹni to tun jẹ Akinruyiwa tiluu Owu Abẹokuta lo sọrọ naa lakoko ipolongo ojule si ojule to ṣe lọ si ijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode lopin ọsẹ to kọja.

O ni ẹgbẹ oṣelu PDP maa ṣiṣẹ takuntakun bi wọn ba wọle idibo ọdun yii lati rii pe ipinlẹ Ogun de ipo to yẹ ki wọn wa.

Nibẹ lo ti ran awọn eeyan leti nipa awọn idagbasoke alailẹgbẹ to waye lakoko iṣakoso Gomina Gbenga Daniel laaarin ọdun 2003 si ọdun 2007.

O tẹsiwaju pe kii ṣe ahesọ tabi asọdun wi pe ipo dakudaji ni ipinlẹ naa wa lasiko yii, to si ni bi awọn araalu ba fi ibo gbe wọn wọle, ayipada rere yoo deba ipinlẹ wọn.

Bakan naa lo tun fi kun ọrọ rẹ pe gbogbo igberiko, abule kaakiri ni iṣakoso PDP yoo ti ṣiṣẹ idagbasoke lai si ọrọ ẹlẹyamẹya nibẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI