Mo dupẹ lọwọ awọn ara Ọṣun ti wọn ko tẹwọ gba idajọ 'BUGA' - Adeleke - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, January 30, 2023

Mo dupẹ lọwọ awọn ara Ọṣun ti wọn ko tẹwọ gba idajọ 'BUGA' - Adeleke


Gomina Ademọla Adeleke ti ipinlẹ Ọṣun ti dupẹ gidigidi lọwọ gbogbo awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ naa, lori bi wọn ko ṣe tẹwọ gba idajọ 'BUGA' to ni ile ẹjọ da lori eto idibo ọdun to kọja nipinlẹ naa, eyi to gbe e wọle gẹgẹ bii gomina.

Adeleke lo fi ẹmi imoore rẹ han s'awọn araalu, paapaa awọn ololufẹ rẹ lonio, ọjọ Aje, Mọnde niluu Oṣogbo.

O sọrọ naa nibi ipade awọn alẹnulọrọ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP to waye lori eto idibo apapọ orileede yii to n bọ ninu oṣu keji, ọdun 2023 ti a wa yii.

Adeleke to gbe ọrọ naa soju opo ayelujara ti Twitter rẹ lo sọ pe inu oun dun, ọkan oun si balẹ wi pe ifẹ araalu ni yoo ṣẹ.

"Ni irọlẹ oni, mo kopa nibi ipade awọn agbaagba ati alẹnulọrọ ẹgbẹ oṣelu PDP, nibi ti a ti jiroro lori awọn ohun to ṣe pataki fun eto idibo to n bọ lọna.

"Mo lo anfaani naa lati dupẹ lọwọ awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun fun aduroti wọn fun bi wọn ko ṣe gba idajọ 'BUGA'."


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI