Ẹ tu Nnamdi Kanu silẹ o, mo ṣetan lati ṣe oniduro fun un - Soludo pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, January 14, 2023

Ẹ tu Nnamdi Kanu silẹ o, mo ṣetan lati ṣe oniduro fun un - Soludo pariwo sita


Gomina Chukwuma Charles Soludo ti ipinlẹ Anambra ti rọ ijọba apapọ orileede Naijiria lati tu olori ajijangbara Biafra, Nnamdi Kanu silẹ lahamọ to wa.

Soludo loun ṣetan lati duro fun un gẹgẹ bi oniduro, bi ijọba apapọ ba le yọnda rẹ foun, to si loun yoo ṣe gbogbo ohun to ba yẹ lati ṣe.

Gomina naa lo sọrọ yii nibi ipolongo idibo ti wọn ti fi oju oludije sipo Aarẹ Naijiria, Ọjọgbọn Peter Umeadi han fawọn araalu.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe; "Mo n bẹ ijọba apapọ tọkantọkan lati fi Nnamdi Kanu silẹ lai nidii. Bi ijọba ko ba le fi silẹ lai nidii, mo fẹ ki wọn tuu silẹ, maa si ṣe oniduro fun un.

"A nilo Nnamdi Kanu nibi ipade apero lati sọrọ nipa eto aabo ẹkun South East. A ni lati fi opin si gbogbo aisi eto aabo, a si fẹ ki Nnamdi Kanu wa nibẹ."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI