Nnkan de! Olu-ileeṣẹ ọlọpaa jona lọsan gangan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, January 14, 2023

Nnkan de! Olu-ileeṣẹ ọlọpaa jona lọsan gangan


Ṣe ni ọrọ di boolọ o yago lọna nigba ti wọn ni olu-ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kano to wa lagbegbe Bompai, ijọba ibilẹ Nasarawa bẹrẹ sii jona lọsan gangan.

Awọn ọfiisi, iwe to ṣe pataki la gbọ pe wọn ba ijamba ina ọhun lọ.

Wọn ni aṣọ ko ba ọmọyẹ mọ nigba ti awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana ti wọn ranṣẹ pe yoo fi de.

Agbegbe kan ni apa oke ileeṣẹ ọlọpaa naa ni wọn lo jona, to si jo ọpọ ọfiisi, to fi mọ dukia at'awọn iwe to ṣe pataki nibẹ.

Bo tilẹ jẹ pe a ko tii le fidi rẹ mulẹ lẹkunrẹrẹ, sibẹ a gbọ pe bi awọn ọfiisi ọhun ṣe jona to, ko de ọfiisi ọga ọlọpaa ipinlẹ naa, Mamman Dauda.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI