Ẹ yee ko owo atijọ sẹnu ATM mọ - Awọn alaṣẹ CBN kilọ f'awọn banki - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, January 10, 2023

Ẹ yee ko owo atijọ sẹnu ATM mọ - Awọn alaṣẹ CBN kilọ f'awọn banki

 
Automated Teller Machines (ATMs) urged commercial banks in the country to comply with the directive of loading the newly redesigned naira notes in their Automated Teller Machines (ATMs).

Wọn ni owo titun ti wọn ko jade lati oṣu kejila, ọdun to kọja l'awọn eeyan nilo lati maa na lasiko yii, nitori pe ọjọ ko ni pẹẹ lọ lori awọn owo atijọ naa mọ.
 
Alakoso eto owo ni banki agba naa (Director of Currency Operations), Ọgbẹni Ahmẹd Umar lo sọ eyi di mimọ niluu Abuja lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, iyẹn nibi idanilẹkọọ to ṣe f'awọn alakoso banki naa lorileede Naijiria, pẹlu ajọ National Orientation Agency (NOA) lori ọrọ owo tuntun naa.
 
O ni gbogbo awọn banki gbọdọ dẹkun kiko owo atijọ sinu awọn ẹrọ ATM naa mọ, tabi ki wọn foju winna ofin.
 
nibẹ lo tun ti jẹ ko di mimọ pe ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kinni, ọdun 2023 ti a wa yii ni gbedeke ọjọ t'awọn owo atijọ naa yoo wa nita fun lilo.
 
"Awa alaṣẹ CBN ti pa a laṣẹ fun gbogbo banki lati dẹkun kiko awọn owo atijọ sẹnu ẹrọ ATM wọn mọ. Ki wọn maa ko owo tuntun sibẹ.
 

"O si ni ṣisẹ-n-tẹle bi wọn ṣe le ko owo sibẹ. Wọn le ko ẹẹdẹgbẹta naira, ẹgbẹrun kan naira tabi igba naira, eyikeyi owo to ba wu wọn ni wọn le ko sẹnu ẹrọ ATM wọn, ki wọ ṣaa ti ko owo tuntun sibẹ.
 
"A ma maa tọpinpin bayii lati rii pe awọn banki tẹle ilana yii, ati pe bi wọn ko ba tẹle e, wọn yoo foju winna ofin wi pe wọn ko tẹle ilana ati aṣẹ."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI