Awọn ọmọ Naijiria nilo 'Ahun' fun idagbasoke ati ilọsiwaju - Peter Obi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, January 10, 2023

Awọn ọmọ Naijiria nilo 'Ahun' fun idagbasoke ati ilọsiwaju - Peter Obi

Oludije s'ipo aarẹ orileede yii labẹ asia ẹgbẹ Labour, Peter Obi ti sọ pe ahun nikan l'awọn ọmọ orileede Naijiria nilo lati mu idagbasoke ati ilọsiwaju ba ilẹ wọn.
 
Peter Obi lo sọrọ naa loni, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹwaa, oṣu kinni, ọdun 2023, nigba to n tako ọrọ awọn alatako rẹ, Atiku Abubakar ati Bọla Ahmẹd Tinubu.
 
Tinubu ati Atiku ni wọn bu ẹnu atẹ lu Obi wi pe ahun ni, ko si ni ohunkohun to fẹẹ ṣe f'awọn ọmọ Naijiria.
 
Ṣugbọn nigba toun naa n sọrọ, o loun ko jẹ ẹnikẹni ni ẹbẹ nitori pe oun lahun.
 
O ni oun nikan ni oludije to kere julọ lọjọ ori, toun si tun ni okun ati agbara lati ṣakoso orileede yii laaarin gbogbo awọn ti wọn jọ n dije.
 
Nibi ipade to ṣe pẹlu awọn igbimọ lọbalọba n'iluu Anambra, ipinlẹ Akwa lo ti sọrọ naa jade.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI