Ẹbun Ọdun: Ileeṣẹ Pelican fun awọn oṣiṣẹ rẹ ni ilẹ olowo iyebiye l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, January 3, 2023

Ẹbun Ọdun: Ileeṣẹ Pelican fun awọn oṣiṣẹ rẹ ni ilẹ olowo iyebiye l'Ogun


Ọrọ Yoruba kan to sọ pe 'Inu didun lo n mu koriya wa' gan-an lo lọ ni ibamu pẹlu bi gbajugbaja ileeṣẹ kan to n ri si ọrọ ilẹ ati dukia tita, iyẹn Pelican Valley Nigeria Limited ṣe fi ẹbun ilẹ olowo iyebiye ta awọn oṣiṣẹ rẹ lọrẹ.
 
Ko si nnkan meji ti a gbọ pe o mu ki alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ naa, Ọmọwe Babatunde Adeyẹmọ fi ẹbun rabandẹ naa ta awọn oṣiṣẹ wọnyi lọrẹ, bi ko ṣe bi wọn ṣe n ṣiṣẹ wọn gẹgẹ bi iṣẹ, ti wọn ko si fi iṣẹ ṣere.
 
Nibi ayẹyẹ eto iṣile tuntun ti Ọmọwe Adeyẹmọ ṣẹṣẹ kọ funra rẹ lati maa gbe lo ti fi ẹbun naa ta awọn oṣiṣẹ rẹ meji lọrẹ, lati fi mu koriya ba iṣẹ ti wọn n ṣe.
 
AWIKONKO gbọ pe lara awọn ọna ti alaṣẹ ileeṣẹ naa n gba lati maa fi mu inu awọn oṣiṣẹ rẹ dun ni didasi awọn ohun ti yoo mu igbesi aye wọn tẹsiwaju, nipa fifun wọn ni ọjọ iwaju to dara.
 
Gbogbo awọn iwe to yẹ, to fi mọ iwe ẹri 'emi ni mo ni ilẹ' la gbọ pe Ọmọwe Adeyẹmọ ti ṣe, ko to fa a ilẹ ọhun le meji lara awọn oṣiṣẹ rẹ lọwọ.
 
Nigba to n sọrọ nipa idi to fi f'ẹbun ilẹ naa ta awọn meji ọhun lọrẹ, Ọmọwe Adeyẹmọ sọ pe awọn meji naa lo peregede julọ lai labawọn ninu gbogbo awọn to n ba a ṣiṣẹ, paapaa f'ọdun 2022 to ṣẹṣẹ kọja yii.

Ọmọwe Adeyẹmọ ni ọwọ ti wọn fi mu iṣẹ wọn lokukudun fi han pe wọn fi ara jin fun iṣẹ ti wọn gba, eyi to n mu itẹsiwaju ba ileeṣẹ Pelican Valley.

Siwaju sii lo sọ pe iwa otitọ ati inukan lo jẹ akọmọna f'awọn mejeeji, to si lo ko ipa rẹpẹtẹ ninu itẹsiwaju ileeṣẹ wọn, eyi to loo di dandan lati fi ẹmi imoore han si wọn.
 
Awọn meji ọhun naa ni Ọgbẹni Ọpẹyẹmi Adebayọ ati Arabinrin Bọlanle Oluṣiyan.

Nibẹ lo ti wa rọ awọn oṣiṣẹ yooku lati fi ọrọ awọn mejeeji yii ṣe arikọgbọn nipa ṣiṣe otitọ, ki wọn si fi iwa ọmọluabi ati ifarajin sinu akọmọna wọn, paapaa l'ọdun tuntun yii, ki ire airotẹlẹ le wọle tọ wọn wa.
 
Siwaju sii nigba to n sọrọ lori ile to ṣẹṣẹ ṣi naa, Ọmọwe Adeyẹmọ sọ pe ọdun mẹjọ loun fi farabalẹ kọ ile ọhun lai kan ara oun loju, koun le gbadun rẹ di ọjọ alẹ.
 
O ni ile nla loun fi silẹ kuro niluu Eko lati le jẹ koun gbajumọ ọrọ ile ara oun, fun igbadun ọjọ alẹ oun ati mọlẹbi oun.
 
Arabinrin Adedọtun Adehinbọ, ọkan lara awọn onibara ileeṣẹ Pelican, ẹni to ti n gbe inu ile rẹ to ra ilẹ rẹ lara ilẹ Pelican Estate, o ni abamọ ni yoo pada jẹ foun ka loun ko ra ilẹ lọwọ Pelican, nitori pe itẹsiwaju lo de ba oun latigba toun ti ba ileeṣẹ naa dowo pọ.
 
Aṣoju ileeṣẹ Pelican, Ọgbẹni Kayọde Ọlaṣeinde, gbajugba oṣere-adẹrinpoṣonu ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Pa Ajirebi ninu ọrọ tiẹ naa sọ pe idunnu nla lo maa n jẹ foun nigbakugba toun ba n ranti pe ileeṣẹ Pelican loun n ṣoju rẹ.
 
O ṣapejuweỌmọwe Adeyẹmọ gẹgẹ bii olotitọ eeyan, ti kii sii fi igba kan bo ọkan ninu f'eeyan, eyi to loun gan-an lo n mu itẹsiwaju ati idagbasoke ba ileeṣẹ rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI