Ogunlọgọ awọn ọmọ ẹgbẹ ọlọkada, onimọto, to fi mọ awọn oniṣẹ ọwọ ati oniṣowo n'ipinlẹ Kwara ni wọn ti kede sita gbangba wi pe awọn ti pada lẹyin ijọba Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba orileede yii tẹlẹ, Sẹnetọ Bukọla Saraki, ti wọn si l'awọn yoo tẹsiwaju lati maa gbaruku ti ijọba Gomina AbdulRahman AbdulRazaq.
Wọn ni ko si nnkan to tun le jẹ k'awọn tẹle Saraki mọ nipinlẹ Kwara nitori pe asiko rẹ gẹgẹ bii gomina ko tẹ awọn lọrun.
Ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kinni, oṣu kinni, ọdun ti a wa yii l'awọn eeyan naa korajọ niluu Ilọrin lati ṣatilẹyin fun ipolongo idibo ẹlẹẹkeji fun Gomina AbdulRazaq.
Nibẹ ni wọn ti ko gbogbo fila, aṣọ ati awọn ohun idanimọ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, ti wọn si dana sun wọn, eyi ti wọn fi n sọ pe awọn ko tun ni nnkan lati ṣe pẹlu ẹgbẹ oṣelu naa mọ.
Awọn fila ti wọn kọ 'O'su wa' sii la gbọ pe ẹgbẹ PDP pin f'awọn eeyan lati maa sọ pe ijọba APC ti su wọn nipinlẹ naa, ki wọn ba a le ṣatilẹyin fun wọn ninu ibo ọdun yii.
Gbogbo rẹ si la gbọ pe awọn araalu dana sun patapata lai ku ẹyọkan ṣoṣo.
Awọn aja awọn ko tun gbọdọ pada s'idi eebi iṣakoso Saraki mọ lailai, nitori pe ko mu itẹsiwaju ba kwara, paapaa igbesi aye, bi ko ṣe pe wọn fi n gba ọjọ ọla to dara kuro lọwọ wọn.
No comments:
Post a Comment