Kayeefi nla lọrọ baba agbalagba, ẹni aadọta ọdun kan, Ojo Ogundeji, ẹni to dana sun ara rẹ lọsan gangan ṣi n jẹ f'awọn araalu Ondo, paapaa awọn to gbọ si iṣẹlẹ ọhun kaakiri agbaye.
Ojo la gbọ pe o dana sun ara rẹ ninu ninu ile baba rẹ to wa lagbegbe Ọlọruntẹdo to wa n'ijọba ibilẹ Ondo West, ipinlẹ Ondo latari bo ṣe l'awọn eeyan n fi oun ṣẹlẹya.
Ko pẹ ti wọn sọ pe Ojo de lati iilu Eko, nibi to ti lọ b'awọn mọlẹbi ẹ ṣayẹyẹ ọdun to kọja yii.
Lara awọn to fi iṣẹlẹ naa to wa leti sọ pe lati aarọ ọjọ naa ni Ojo ti n gbero lati gbẹmi ara rẹ, ṣugbọn to jẹ iṣoro fun un nitori awọn ara adugbo.
Wọn ni asiko ti ẹsẹ pa lọlọ ni Ojo lọ tilẹkun mọri, to si dana sun ara rẹ mọ inu yara, ko to di pe awọn eeyan sare debẹ lati doola ẹmi ẹ, bo tilẹ jẹ pe aṣọ ko ba ọmọyẹ mọ.
Ojo nigba ti wọn n beere idi to fi fẹẹ pa ara rẹ danu sọ pe awọn eeyan n f'oun ṣẹlẹya nitori aleebu ati iṣoro toun ni, to si lo n ti oun loju kiri ni gbogbo igba.
Wọn lo sọ pe boun ko ba si laye mọ nikan lo le di awọn ẹlẹya naa ku.
Arabinrin Sabaina Ogundeji, lara awọn ẹni ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe:
“Laaarọ, Ojo dana si abẹ siteepu to wa ninu ile, o si lẹnikẹni ko gbọdọ pa ina ọhun. Ṣugbọn nipa iranlọwọ awọn araadugbo, wọn pa ina naa.
“Nigba to di ọwọ irọlẹ, gbogbo eeyan wa nita, a n ṣere. Ojo wọ inu ile lọ, o si lọ ko awọn aṣọ rẹ jade, to si dana sun wọn niwaju ita. Lẹyin naa lo wọ inu ile lọ, o ti ara mọ inu ile, ko to dana sun ara mọ inu ile. Ariwo to n pa lakoko ti ina ọhun muu lara lo jẹ ka sare lọ sinu ile lati mọ ohun to n ṣẹlẹ. Awọn eeyan lo fi agidi ja ilẹkun wọle, ti wọn si gbe e jade. Ọsibitu ti wọn gbe e lọ lo pada ku si.”
Ẹlomiran ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju ẹ sọ pe;
“Nigba ti a dola ẹmi ẹ, ko tii ku. O sọ fun wa pe nitori t'awọn kan n foun ṣe yẹyẹ nitori iṣoro ati ipenija toun ni, lo jẹ koun pinnu lati gbẹmi ara oun.”
Ẹni ọhun lo jẹ ka mọ pe wọn ti gbe oku rẹ lọ mọṣuari ọsibitu ijọba to wa ni Ondo.
No comments:
Post a Comment