2023: Awọn onilu l'awọn yoo ṣatilẹyin ibo fun Aderinokun, oludije sipo aṣofin agba lorileede Naijiria - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, January 14, 2023

2023: Awọn onilu l'awọn yoo ṣatilẹyin ibo fun Aderinokun, oludije sipo aṣofin agba lorileede Naijiria


Bi ṣẹkẹrẹ kii ṣe e ba wọn lọ s'ode ibanujẹ, bẹẹ naa ni ilu kii ba wọn lọ s'ode ọfọ, eyi lo mu ki ẹgbẹ awọn onilu ti wọn pe ara wọn ni Ọpapeju Drummers Association sọ pe awọn ṣetan lati ṣatilẹyin ibo fun oludije sipo ile igbimọ aṣofin agba lorileede Naijiria lati ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun, Olumide Aderinokun.

Ẹgbẹ naa sọ pe ẹnikan ṣoṣo ti awọn le fi ọwọ rẹ sọya wi pe yoo ṣe daadaa laaarin awọn oludije yooku ni Aderinokun, ẹni to n dije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP.

Nibi ipade ti ẹgbẹ naa ṣe pẹlu Aderinokun lonii ọjọ Abamẹta, Satide, eyi to waye lagbegbe Ijaye niluu Abẹokuta ni wọn ti fi ontẹ lu ọkunrin naa gẹgẹ bi oludije to peregede.

Ẹgbẹ naa ti Oloye Sulaimọn Oseni jẹ olori wọn sọ pe gbogbo ohun ti yoo ba gba l'awọn yoo ṣe lati rii pe awọn araalu jade dipo fun Aderinokun ni gbogbo ijọba ibilẹ mẹfa to so aarin gbungbun papọ.

Nibẹ ni gbogbo awọn adari ẹgbẹ oṣelu PDP kaakiri ijọba ibilẹ mẹfa to wa ni aarin gbungbun ipinlẹ Ogun naa ti fi da oludije wọn loju wi pe gbogbo eto lo n lọ labẹlẹ, lati rii pe o jawe olubori.

Aderinokun ninu ọrọ rẹ dupẹ gidigidi lọwọ awọn ẹgbẹ naa, to si ṣeleri wi pe oun ko nii ja wọn kulẹ bi oun ba wọle, nitori pe ifẹ araalu lo jẹ oun lọkan.

Bẹẹ lo sọ pe ẹdun ọkan lo maa n jẹ foun, nigba toun ba rii pe awọn eeyan wa ninu iṣẹ ati oṣi, ti wọn ko si jẹ igbadun mudunmudun eto iṣejọba awa-ara-wa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI