Ẹgbẹ awọn olukọ, Nigeria Union of Teachers n'ipinlẹ Kwara ti gbe oṣuba kare fun gomina wọn, AbdulRahman AbdulRazaq lori awọn ipa to n ko ninu eto idagbasoke ipinlẹ naa, paapaa ile igbalode to tun fẹẹ kọ fun gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ wọn.
Wọn ni igbesẹ ti gomina naa bẹrẹ ko tii ṣẹlẹ ri, akọkọ iru ẹ ni wọn pe e, ti wọn si ni inu idunnu ati ayọ nla l'awọn olukọ wa.
Alaga ẹgbẹ awọn olukọ n'ipinlẹ naa, Kọmureedi Oyewọ Muhammad Bashir, nigba to n gba ẹnu awọn olukọ sọrọ, sọ pe ohun iwuri nla gomina ṣe fun wọn.
O ni gbogbo awọn ẹtọ, owo oṣu ati ajẹmọnu ni Gomina AbdulRazaq n san fun wọn lasiko, eyi ti ko ṣẹlẹ tẹlẹ l'awọn asiko iṣakoso to kọja.
Yatọ si eyi, o tun jẹ ko di mimọ pe iṣẹ tun ti n lọ l'awọn ile ẹkọ kaakiri, nipa atunkọ awọn ile ẹkọ to ti dẹnukọlẹ.
O ni ile ti gomina n kọ lọwọ fun gbogbo awọn olukọ ti fi han gomina naa karamasiki ọjọ alẹ gbogbo wọn, to si gbe oṣuba rabandẹ fun un.
No comments:
Post a Comment