OGUN: Aderinokun, oludije s'ipo aṣofin agba tun fẹẹ gba fọọmu JAMB fun ẹgbẹrun kan akẹkọọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, January 24, 2023

OGUN: Aderinokun, oludije s'ipo aṣofin agba tun fẹẹ gba fọọmu JAMB fun ẹgbẹrun kan akẹkọọ


Gbogbo eto lo ti pari patapata, to si tun ti n lọ pẹlu, eyi ti gbajugbaja oloṣelu ipinlẹ Ogun nni, Olumide Aderinokun, ṣe fi oju opo f'awọn akẹkọọ to ba fẹẹ ṣe idanwo JAMB lelẹ lati fi orukọ silẹ nibẹ.

Kii ṣe akọkọ ree ti Aderinokun yoo maa gbe iru awọn eto bayii kalẹ, lati fi ṣe iranlọwọ fawọn eeyan paapaa awọn akẹkọọ, eyi to n mu irọrun b'awọn obi.
 
Awọn akẹkọọ ti ko din ni ẹgbẹrun kan, kaakiri ijọba ibilẹ mẹfa to wa ni aarin gbungbun ipinlẹ Ogun la gbọ pe Aderinokun, oludije s'ipo aṣofin agba l'Abuja lati ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party (PDP) fẹẹ ṣe iranwọ naa fun.

Gbogbo awọn akẹkọọ ti wọn ba a fẹ ṣe idanwo aṣewọle si ile ẹkọ giga, yala fasiti, gbogboniṣe tabi kọlẹẹji, iyẹn Joint Admission and Matriculation Board (JAMB) ni wọn lanfaani lati tete fi orukọ silẹ.
 
Ọjọ kẹwaa, oṣu keji, ọdun 2023 ni eto iforukọsilẹ naa yoo kasẹ nilẹ, gẹgẹ bi a ṣe gbe.
 
Ninu atẹjade ti amugbalẹgbẹẹ Aderinokun lori ọrọ iroyin, Ọgbẹni Taye Taiwo fi ranṣẹ s'AWIKONKO, o ni oju opo https://aderinokunfoundation.org/free-jamb-form/ l'awọn akẹkọọ yoo ti fi orukọ wọn silẹ.
 
 
Fi orukọ silẹ nibi: FỌỌMU JAMB ADERINOKUN
 
Taiwo ni gẹgẹ bi ẹ ti mọ pe eto ẹkọ jẹ Aderinokun logun pupọ, eyi lo jẹ ko ṣe iranwọ gbigba fọọmu JAMB naa f'awọn ogun akẹọọ lọdun 2022, to si tun ṣe iranwọ ẹgbẹrun lọna aadọta naira fun aadọta akẹkọọ kaakiri aarin gbungbun ipinlẹ Ogun bakan naa, iyẹn lọdun 2022.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI