Ẹni to tọ ni wọn fi jẹ 'Grand Kadi' ni Kwara - Gomina AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, January 22, 2023

Ẹni to tọ ni wọn fi jẹ 'Grand Kadi' ni Kwara - Gomina AbdulRazaq


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti  sọ pe ẹni to tọ ni wọn yan fun ipo olori ile ẹjọ kọtẹmilọrun ti Ṣaria, iyẹn Grand Kadi, Shariah Court of Appeal, Onidajọ Abdullateef Kamaldeen.

Onidajọ Kamaldeen ni wọn ṣẹṣẹ bura fun gẹgẹ bii Grand Kadi lọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii niluu Ilọrin, lẹyin ti wọn ti kọkọ yan an gẹgẹ bi adele lọjọ kẹrindinlogun, oṣu keji, ọdun 2022 to kọja, ni kete ti ONidajọ agba ile ẹjọ naa tẹlẹ, Onidajọ Muhammad Ọla AbdulKadir fẹyinti.

Nigba to n sọrọ, gomina naa sọ pe ẹni ti ipo naa tọ si ni wọn yan, ti igbagbọ si wa pe yoo ṣe daadaa ju b'awọn eeyan ṣe lero lọ, ati pe yoo tọ ipasẹ awọn agba Onidajọ to ti kọja lọ.
 
Bẹẹ lo gbadura pe ki adẹdaa fun un ni ọgbọn, imọ ati oye lati dari ile ẹjọ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI