Eto ilera: Banki agbaye gbe owo nla kalẹ fun ijọba Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, January 22, 2023

Eto ilera: Banki agbaye gbe owo nla kalẹ fun ijọba Kwara


Lojuna lati jẹ k'awọn araalu jẹ eto ilera igbalode alailabawọn, awọn alaṣẹ banki agbaye ti gbe owo iranwọ nla kalẹ fun ijọba ipinlẹ Kwara lati loo fun idagbasoke eto ilera alabọde. 
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni banki agbaye naa gbe owo yii kalẹ fun kikọ awọn ibudo eto ilera ti oloyinbo n pe ni Health Centres kaakiri wọọdu mẹtalelaadọwa, 193 to wa nipinlẹ naa.

Ọla tii ṣe ọjọ Aje, ọjọ kẹtalelogun, oṣu kinni, ọdun 2023 yii ni gomina AbdulRazaq yoo fi eto ọhun lelẹ, ti gbogbo awọn alakoso ibudo eto ilera, iyẹn Primary Health Centres yoo ti maa gba iwe sọwedowo ti wọn yoo fi bẹrẹ akanṣe iṣẹ naa.

Nigba to n fidi rẹ mulẹ ninu atẹjade, Dọkita Nusirat Elelu, to jẹ akọwe ajọ to n ri sọrọ eto ilera nipinlẹ naa, Kwara State Health Care Development Agency, o ni miliọnu N887,800,000 ni yoo ba eto ti wọn pe ni Immunisation Plus and Malaria Progress by Accelerating Coverage and Transforming Services (IMPACT) lọ, eyi to ni ijọba ti san lara rẹ tẹlẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI