Haaaaaa! Gbajumọ ile igbafẹ jona di eeru l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, January 16, 2023

Haaaaaa! Gbajumọ ile igbafẹ jona di eeru l'Abẹokuta


Ariwo 'Ẹ gba wa ooooo' lo gba ẹnu awọn ara agbegbe Nawair-Ud-Deen to wa lagbegbe Isalẹ Ọja Kutọ niluu Abẹokuta loru oni, nigba ti wọn sọ pe ile kan to wa nibẹ jona.

Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii la ko tii le sọ pato ohun to ṣokunfa ijamba ina naa, ṣugbọn sibẹ, wọn ni gbogbo dukia inu ile ọhun lo jona kọja sisọ.

Ile naa ni wọn lo wa lẹgbẹ ile igbafẹ kan to gbajumọ nibẹ daadaa, iyẹn ile igbafẹ ti wọn l'awọn to fẹran ọti ti maa n mu ọti kan ti wọn n pe ni Burukutu.

AWIKONKO gbọ pe ko sẹni to farapa tabi jona mọle, ṣugbọn awọn eeyan to n gbe inu ile naa ko ri ohunkohun mu jade.

Wọn ni ẹpa ko boro mọ k'awọn oṣiṣẹ panapana too debẹ. Bo tilẹ jẹ pe wọn pada pa ina yooku.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI