Ọwọ tẹ Tunde to lu iya ẹlẹja pa nitori ọgọrun naira n'Ijẹbu Ode - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, January 16, 2023

Ọwọ tẹ Tunde to lu iya ẹlẹja pa nitori ọgọrun naira n'Ijẹbu Ode


'Ẹ ṣe mi jẹjẹ, ẹ foju aanu wo mi, iṣẹ eṣu ni', lọrọ ẹbẹ to n jade lẹnu gendekunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Tunde, ẹni ti wọn lo lu obinrin kan to n ta ẹja pa.

B'awọn kan ṣe n sọ pe ẹfun ni, bẹẹ l'awọn miran n sọ pe eedi ni, ti awọn miran si n jẹ ko di mimọ pe kii ṣoju lasan.

Gẹgẹ bi a gbọ, wọn ni obinrin ẹlẹja naa lo n kiri lọ lagbegbe Imoru, iyẹn l'Ọjọbọ, Tọsidee, ko to di pe Tunde pe e lati ra ẹja lọwọ ẹ.

Wọn ni ẹgbẹta (₦600) naira ni ẹja ti Tunde nọwọ si, ṣugbọn to ni ẹẹdẹgbẹta (₦500) naira loun yoo san. 

Lẹyin eyi ni wọn ni Tunde mu ẹja naa, to si fun obinrin naa ni ẹẹdẹgbẹta naira, loju ẹsẹ ni wọn lo ti n jẹ ẹja ọhun, pẹlu erongba wi pe ko ni ṣee gba pada.

Pẹlu ibinu ni wọn sọ pe obinrin ẹlẹja naa fi di Tunde ni aṣọ mu, to si loun yoo gba owo oun ni tipatipa. 

Aṣọ ti wọn ni obinrin naa di mu lo bi Tunde ninu to fi bẹrẹ sii ko igbaju ati igbamu bo o, to si n lu bi ọmọde, ko to di pe awọn eeyan sare sunmọ wọn.

Wọn ni bawon eeyan ṣe sunmọ wọn to, Tunde ko dẹkun lilu obinrin naa, tiyẹn si ṣe bẹẹ mu idi lọ silẹ, ko too daku.

Ere ni wọn l'awọn eeyan kọkọ pe e, to mu ki wọn sare da omi lee lori, ṣugbọn ti ẹpa ko boro mọ, wọn l'obinrin naa ti wa eyin lu.

Loju ẹsẹ ti Tunde ti ri ohun to ṣẹlẹ yii lo ti na papa bora, ti wọn ko si rii mu. Eyi lo mu ki wọn lọ fi iṣẹlẹ ọhun to ileeṣẹ ọlọpaa ẹkun Igbeba leti, ko to di pe wọn gbe oku obinr naa lọ mọṣuari.

Ko ju bi wakati kan lẹyin la gbọ pe awọn eeyan kofiri Tunde ni opopona marosẹ Eko si Benin, iyẹn lagbegbe Ejinrin, nibi to ti n gbiyanju lati wọ mọto salọ kuro niluu Ijẹbu-Ode.

Loju ẹsẹ ti wọn kofiri rẹ ni wọn ti mu, ti wọn si lọ fa a le awọn ọlọpaa lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI