Ibi iṣẹ ni iyaale ile n lọ, ko to dawati l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, January 10, 2023

Ibi iṣẹ ni iyaale ile n lọ, ko to dawati l'Abẹokuta


Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni ko tii sẹni to le sọ pato ibi ti iyaale ile ti ẹ n woju rẹ yii wa, latigba to ti jadee kuro nile.

AWIKONKO gbọ pe agbegbe Gbọnagun to wa ni Ọbantoko ni obinrin naa, Arabinrin Adeboye Olubukọnla Arikẹ ti wọ ọkọ taisi, to si n lọ si agbegbe Iṣabọ, iyẹn niluu Abẹokuta.
 
Wọn ni olukọ ilẹ ẹkọ alakọbẹrẹ F Kuti to wa ni wọn pe Arabinrin Arikẹ.
 
Latigba ti wọn lo ti wọ taisi naa laaarọ ana, ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹsan, oṣu kinni, ọdun 2023 ti a wa yii ni ko ti sẹni to le sọ pato ibi to wa.
 
Inu idaamu ati iporuru ọkan lawọn mọlẹbi rẹ wa bayii, nitori ti wọn sọ pe ko tiii sẹni to pe wọn, yala lati beere owo tabi ohunkohun lọwọ wọn.
 
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun la gbọ pe wọn ti gbọ si iṣẹlẹ naa, ti wọn si ti bẹrẹ iṣẹ iwadii, bo tilẹ jẹ alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Abimbọla Oyeyẹmi ko ti i sọ ohunkohun nipa rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI