Oludije s'ipo aarẹ orileede Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Bọla Ahmẹd Tinubu ti ṣeleri fun gbogbo awọn ọmọ Naijiria wi pe iyanṣẹlodi ẹgbẹ awọn olukọ fasiti, iyẹn Academic Staff Union of Universities, ASUU, ko nii waye lakoko iṣekọba oun.
Tinubu lo sọrọ naa niluu Damaturu, ipinlẹ Yobe nibi ipolongo idi aarẹ to waye nibẹ.
O ni gbogbo ohun to ba maa fa iyanṣẹlodi tabi aawọ loun yoo gbegidina rẹ patapata ninu eto ilana fasiti.
Bakan naa lo tun ṣeleri pe oun yoo gbe eto ẹyawo kalẹ f'awọn akẹkọọ fasiti patapata, eyi ti yoo jẹ ki eto ẹkọ wọn rọrun.
No comments:
Post a Comment