Igbimọ ẹgbẹ Baalẹ ilu Orile-Ilawo f’atilẹyin han si ọba tuntun, Macgregor - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, January 22, 2023

Igbimọ ẹgbẹ Baalẹ ilu Orile-Ilawo f’atilẹyin han si ọba tuntun, Macgregor


Awọn Baalẹ ti ko din ni marundinlaadọrin to wa niluu Orile-Ilawọ, ijọba ibilẹ Ọdẹda nipinlẹ Ogun ni wọn ti lọ fi atilẹyin wọn han si ọba tuntun ti wọn dibo yan fun wọn laipẹ yii, Oloye Oluṣẹgun Alexandar Macgregor, ti wọn si lawọn ṣetan lati fọwọsowọpọ pẹlu iṣakoso rẹ gẹgẹ bi ọba wọn.

 
Wọn ni ko si ẹnikankan to tun le mu idagbasoke ati ilọsiwaju ba ilu Orile-Ilawọ ati agbegbe ẹ, bi ko ṣe Oluṣẹgun Macgregor, nitori pe ko si lara awọn to n ta ilẹ ilu lọna aitọ ati ajagungbalẹ ti wọn n ṣakoso ilu naa tẹlẹ.

Ọjọ Ẹti, Furaidee to kọja yii l'awọn Baalẹ naa lọ ṣe abẹwo 'A wa lẹyin rẹ' si ọba tuntun naa ni ile rẹ, Macgregor Heritage House to wa niluu Abẹokuta.

Nibẹ ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe awọn mọ ipa ati ipinnu rere Ọba tuntun naa yoo ko ninu eto idagbasoke ilu naa, paapaa nipa awọn ohun to n jẹ wọn niya niluu Orile-Ilawọ.
 
Wọn ni lara awọn ohun to n mu ifasẹyin ba ilu naa ni opopona ti ko ja geere, aisi ọja, awọn ohun amuṣagbara, ironilagbara, ati aisi eto ipe to ja gaara, eyi ti oloyinbo n pe ni network-mast.
 
Nigba to n gba ẹnu awọn Baalẹ naa sọrọ, Oloye Mukaila Ajasa Ọladunjoye to jẹ alaga gbogbo awọn Baalẹ Orile-Ilawọ sọ pe o di dandan f'awọn lati fi atilẹyin han si ọba tuntun naa, nitori pe ilọsiwaju ilu naa lo jẹ wọn logun.

O lawọon Baalẹ mẹrindinlogọjọ, 156 lo wa niluu Orile-Ilawọ, to si jẹ pe gbogbo wọn lawọn ṣatilẹyin fun Macgregor, yatọ si awọn diẹ to sọ pe wọn ko gba tiẹ, nitori iwa buruku ọwọ wọn.

Siwaju sii lo sọ pe awọn to lọwọ si ilẹ tita nikan ni wọn ko gba ti Macgregor, nitori ti wọn mọ pe ko fẹran tita dukia danu lọna aitọ, bẹẹ si ni ko nii gba wọn laaye lati ta ilẹ onilẹ to ba gun ori itẹ.

O wa rawọ ẹbẹ sijọba ipinlẹ Ogun labẹ Gomina Dapọ Abiọdun lati tete bu ọwọ lu Macgregor fun wọn, ki wọn si le tete ṣeto ayẹyẹ igbade ko to pẹ ju, nitori pe ko si ohun to n da wọn duro mọ, niwọn igba ti gbogbo ilu ti fọwọ si ẹni ti wọn n fẹ.


Ninu ọrẹ, Ọba tuntun naa, Oluṣẹgun Alexandar Macgregor dupẹ gidigidi lọwọ awọn Baalẹ naa fun aduroti wọn, to si lo jẹ iyalẹnu wi pe wọn dide lati wa ṣatilẹyin f'oun.

O gba wọn lamọran lati ṣe ara wọn ni oṣuṣu ọwọ, ki wọn si fi ifẹ ba ara wọn lo pẹlu iṣọkan, nitori pe nipa iṣọkan ati ifẹ ni ilu Orile-Ilawọn le fi ni ilọsiwaju to peye lai si idiwọ.

Bakan naa lo sọ pe gbogbo awọn nnkan to n jẹ wọn niya loun mọ patapata, pẹlu ileri wi pe oun yoo ṣe gbogbo rẹ fun wọn laipẹ, ti gbogbo wọn yoo si bọ sinu igbadun ayeraye.

Lara awọn to tun wa nibi ipade naa ni Osi ilu Ilawọ, Oloye Anthony Olufade, Akọgun ilu Ilawọ, Oloye Wasiu Balogun, to fi mọ awọn ọdọ ilu Orile-Ilawọ lapapọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI