Ẹ wa gbọ o! Wọn ka ori oku mẹta mọ baale ile lọwọ l'Ekoo, lo ba loun ri wọn he ni - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, January 22, 2023

Ẹ wa gbọ o! Wọn ka ori oku mẹta mọ baale ile lọwọ l'Ekoo, lo ba loun ri wọn he ni


Beeyan ba ri baale ile, ẹni ọdun marundinlaadọta kan, Rasaki Aṣiwaju nibi to ti n dọbalẹ rababa niwaju awọn ọlọpaa l’ọsẹ to kọja yii, yoo ro pe alawada kan ni, ko nii mọ pe ọwọ palaba rẹ lo segi.
 
Awọn ọrọ awada lo n t’ẹni Rasaki jade nigba ti akara rẹ tu s’epo pẹlu ori oku mẹta ọtọọtọ ti wọn ka mọ ọn lọwọ lagbegbe Ayọbọ n’ipinlẹ Eko.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni awọn ọlọpaa lo fura si Rasaki to gbe baagi kan dani lagbegbe Ayọbọ l’ọsẹ to kọja yii, ti wọn si daa duro lati beere ohun to wa ninu baagi ọwọ ẹ.
 
Loju ẹsẹ ti wọn ti beere ibeere naa la gbọ pe Rasaki ti n gbọn lohun, ti ko si le sọrọ. Eyi lo jẹ ki wọn sọ fun un pe ko da ohun to wa ninu baagi ọhun silẹ.
 
Wọn ni loju ẹsẹ ni Rasaki ti kunlẹ, to si n dọbalẹ bẹbẹ pe ki wọn foju aanu wo oun, nitori pe oun ko mọ pe aṣiri ori oku toun ko dani yoo pada tu sita.
 
Nigba to n ṣalaye ibi to ti ri awọn ori oku mẹta naa f’awọn ọlọpaa, o ni inu kọta loun ti ri wọn lagbegbe Ayọbọ nibẹ, ati pe oun kan ko wọn ni, toun si fẹẹ koo lọ sile.
 
O ni, “Ẹ ṣaanu mi o, baba mi ti ku, baba mi ti ba temi jẹ ko too lọ, mo ri awọn ori oku yii he ninu gọta laaarọ yii ni o, agbegbe Ayọbọ, ni Ipaja, ni mo ti ri wọn he. Haa, aye mi ti bajẹ o, temi ti bajẹ o.
 
“mi o ko wọn lọ sibi kankan o, emi ni mo fẹẹ lo wọn, mo fẹẹ lo wọn fun ara mi ni o. Mo mọ pe mo ti lufin, ẹ jọọ, ẹ ṣaanu mi, aajo ara mi ni mo ni ki n ṣe o.”
 
Nigba to n f’idi iṣẹlẹ naa mulẹ, agbẹnusọ f’awọn ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin, sọ pe otitọ ni iṣẹlẹ ọhun, ati pe Rasaki ti wa lọgba ileeṣẹ wọn to wa ni Yaba, nibi ti wọn ti n fọrọ wa a lẹnu wo lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI