Ijọba l'awọn ti bẹrẹ iwadii lori ọkunrin to pa iyawo rẹ nitori burẹdi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 12, 2023

Ijọba l'awọn ti bẹrẹ iwadii lori ọkunrin to pa iyawo rẹ nitori burẹdi


Ijọba ipinlẹ Anambra ti sọ pe iwadii awọn ti bẹrẹ lori ọkunrin kan,
Wilson Uwadiegwu, ẹni ti iroyin jade sita wi pe o lu iyawo rẹ, Ogochukwu Anene pa nitori burẹdi laipẹ yii.
 
Kọmiṣanna fọrọ awọn obinrin, Ify Obinabo lo sọrọ naa l'Ọjọru, Wẹsidee, ọsẹ yii, lakoko to n gba alejo awọn mọlẹbi oloogbe naa, to fi mọ rẹ, Arabinrin Cordielia Anene lalejo ni ọfiisi rẹ to wa niluu Awka.
 
Ogochukwu Anene, ti ọpọ awọn eeyan tun mọ si Ada Awka la gbọ pe ọkọ rẹ lu pa nitori burẹdi.
 
Nibẹ lo ti sọ pe ijọba ipinlẹ Anambra ti fọwọsowọpọ pẹlu ijọba ipinlẹ Ẹnugu lori iṣẹlẹ kayeefi naa, to si l'awọn yoo ṣe iwadii kikun lati rii pe idajọ ododo waye.
 
O ni 
“ọmọ ipinlẹ Anambra ni oloogbe naa jẹ, ijọba ko si nii dakẹ lori iṣẹlẹ buruku to ba ni lọkan jẹ naa.”
 
Arabinrin Cordelia to jẹ mama oloogbe naa wa kọminu wi pe niṣẹ ni ọkọ ọmọ oun na papa bora ni kete ti iṣẹlẹ ọhun waye, to si bẹbẹ pe ki wọn ma jẹ ki iya naa jẹ oun gbe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI