O tan o! Awọn ọtẹlẹmuyẹ tun ti gbe Doyin Okupe, alakoso eto ipolongo Peter Obi tẹlẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 12, 2023

O tan o! Awọn ọtẹlẹmuyẹ tun ti gbe Doyin Okupe, alakoso eto ipolongo Peter Obi tẹlẹ


Iroyin yajoyajo to tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yii ti sọ pe awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ti gbe alakoso eto ipolonogo idibo aarẹ tẹlẹ fun Peter Obi to n d'ije lẹgbẹ oṣelu Labour.
 
Ohun ti a gbọ ni pe papakọ ofurufu ti Murtala Muhammed to wa niluu Eko ni wọn ti gbe Doyin Okupe laaarọ oni, Ọjọbọ, Tọsidee.
 
Wọn ni ọkan lara awọn agbẹjọrọ Okupe, Tolu Babalẹyẹ ni wọn lo tu aṣiri naa sita wi pe awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ, iyẹn Department of State Security Services ti gbe onibara oun.
 
Ninu ọrọ Babalẹyẹ, o ni
“Iroyin to tẹ mi lọwọ bayii ni pe awọn ọtẹlẹmuyẹ ti gbe Ọmọwe Doyin Okupe ni papakọ ofurufu t'Ekoo. Ilu London lo n lọ ko to di pe wọn daa duro.
 
“Idi ni pe, gẹgẹ bi ẹnikan ṣe sọ fun mi, wọn ni wọon sọ pe ko fi awọn iwe ẹri to sọ pe ile ẹjọ giga l'Abuja ti fi oun silẹ lotitọ han awọn, iyẹn lori ẹsun ti ilẹ ẹjọ ti daa lẹbi, ko si tun san owo itanran, eyi to han si gbogbo agbaye, ko to di pe o lọ sile."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI