Ijọba mẹkunnu ni mo fẹẹ ṣe l'Ogun - Harrison, oludije s'ipo gomina lẹgbẹ AAC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, January 9, 2023

Ijọba mẹkunnu ni mo fẹẹ ṣe l'Ogun - Harrison, oludije s'ipo gomina lẹgbẹ AAC


Oludije s'ipo gomina ipinlẹ Ogun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu African Action Congress, AAC, Ọnarebu Adeyẹmi Harrison ti ṣeleri wi pe oun ko nii ja awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ naa kulẹ, bi wọn ba dibo yan oun gẹgẹ bii gomina l'ọdun yii.

Harrison sọ pe ijọba mẹkunnu loun fẹẹ ṣe, lati rii pe gbogbo araalu jẹ mudunmudun eto oṣelu awaarawa, to si ni ilana toun fẹẹ fi dari ipinlẹ naa ni yoo ṣe anfaani fun t'ọmọde, t'agba.

Siwaju sii lo sọ pe oun yoo fun gbogbo ijọba ibilẹ patapata lanfaani lati maa ṣakoso ara wọn, nitori pe ọna kan ṣoṣo toun mọ pe yoo mu idagbasoke ati ilọsiwaju ba ipinlẹ ati orileede ni ki ijọba ibilẹ da duro.

Ọnarebu Adeyẹmi Harrison, ẹni to ti f'igba kan ri jẹ ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa lati ẹkun Ogun Waterside lo sọ awọn ọrọ wọnyi lakoko to n bura fun awọn igbimọ ipolongo ẹgbẹrun kan rẹ n'ijọba ibilẹ Ọdẹda ati Abẹokuta South l'ọjọ Aiku, Sannde ana.

Nibẹ lo tun ti jẹ ko di mimọ pe gbogbo akẹkọọ lati ile ẹkọ alakọbẹrẹ titi de fasiti ni yoo jẹ anfaani eto ẹkọ ọfẹ labẹ ijọba oun. O ni ko si nnkan to le mu ki awọn eeyan ma jẹ anfaani eto ẹkọ, nitori pe awọn ohun amuṣagbara ati amuṣọrọ wa nilẹ.

"Gbogbo awọn adari wa lonii ni wọn jẹ anfaani eto ẹkọ ọfẹ nigba aye baba wa, Awolọwọ. Mo nii lọkan lati gbe eto ẹkọ ọfẹ kalẹ lati ile ẹkọ alakọbẹrẹ titi de fasiti.

"Awọn ọba naa ni ojuṣe lati ṣe ninu eto  idagbasoke agbegbe wọn, paapaa ilu ti wọn jẹ ọba le lori. Idi ree ti a fi gbọdọ jẹ ki ijọba ibilẹ da duro ninu eto iṣakoso mi. Awọn Baalẹ naa ni ojuṣe lati ṣe, to fi mọ awọn oloye.

"Bi ijọba ibilẹ ko ba da duro, eto idagbasoke soke ko le rọrun f'awọn Ọba, Baalẹ lati ṣe. Koda, alaga ijọba ibilẹ gan-an ko le ri ohunkohun ṣe. Bi wọn ba da duro, eto aabo yoo ṣe daadaa, nitori pe ojuṣe ijọba ibilẹ ni, ko to di pe ijọba ipinlẹ dide iranlọwọ.

"A maa gba awọn eeyan si iṣẹ fun eto aabo, ti a si maa ra awọn irinṣẹ fun wọn, eyi ti yoo jẹ ki iṣẹ wọn rọrun lati koju awọn oniṣẹ ibi. Awọn to n ṣakoso wa lakoko yii ko ni ipinnu ọjọ iwaju rere fun wa, ohun ti wọn yoo jẹ lonii nikan ni wọn mọ.

"Ẹgbẹ oṣelu AAC, ipinnu rere la ni f'awọn araalu. Ijọba mẹkunnu la fẹẹ ṣe, eyi ti yoo jẹ ki gbogbo araalu jẹ anfaani mudunmudun eto oṣelu awaarawa. Ẹyin ti ẹ ko ba tii gba kaadi idibo alalopẹ yin, ẹ tete lọọ gba bayii, nitori pe asiko ti n lọ.

"Eto idibo ti wọle de, oṣu kan ati ọjọ diẹ lo ku bayii. Ẹ jẹ ka jade dibo lati le awọn ẹgbẹ buruku yii kuro n'ijọba, ka si gbe awọn to nifẹẹ araalu lọkan jade."

Bakan naa lo gba gbogbo awọn igbimọ ipolongo rẹ naa lamọran lati fa awọn eeyan wọnu ẹgbẹ naa, ki wọn si jẹ ki wọn mọ pataki awọn anfaani ti wọn yoo jẹ bi wọn ba dibo fun ẹgbẹ AAC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI