Bi awọn eeyan ko ba tete dide fun iranlọwọ iyaale ile kan to loun wa lori ipinnu lati ta ọkan oun fun eṣu, afaimọ ni ki ọrọ ọhun ma pada ri b'awọn eeyan ko ṣe fẹ.
Iyalẹnu nla lo jẹ f'awọn eeyan lori ikanni fesibuuku nigba ti obinrin naa, Arabinrin Ngozi Blessing kọ ọrọ sibẹ wi pe ipenija toun n koju ti fẹẹ kọja agbara oun, toun si ti n ronu lati ta ọkan oun danu fun eṣu.
Ọjọ Abamẹta, Satide, ana ni Blessing kọ ọ sori ikanni awon Kristẹẹni wi pe oun ti ṣetan lati ta ọkan oun danu.
"Mo n ronu lati ta ọkan mi fun eṣu. Awọn ipenija ti mo n koju lasiko yii ti n kọja agbara mi."
"Mo n ronu lati ta ọkan mi fun eṣu. Awọn ipenija ti mo n koju lasiko yii ti n kọja agbara mi."
Bo ṣe kọ ọrọ yii tan, l'awọn eeyan ti bẹrẹ sii gba a niyanju loriṣiriṣi, ti wọn si tun n gbadura fun un.
No comments:
Post a Comment