Ileeṣẹ ọlọpaa orileede Naijiria ti sọ pe awọn ti n wa baba kan to n fun ọmọ rẹ ni igbo mu laipẹ.
Laipẹ yii ni fọnran kan jade sori ikanni ayelujara, nibi ti ọmọkunrin kan ti n fun ọmọ tuntun kekere jojolo ti ko tii ju ọmọ oṣu marun-un lọ ni egboogi oloro, iyẹn igbo mu.
Fọnran naa lo n ya pupọ awọn to rii lẹnu, ti wọn si n fi epe ranṣẹ si i, koda, ti wọn tun n rawọ ẹbẹ si ileeṣẹ ọlọpaa at'awọn eleto aabo lati dide iwadii, ki wọn si f'oju ọkunrin naa j'ofin.
Ninu fọnran naa ni ọkunrin buruku yii ti n kọ ọmọ naa bi wọn ṣe n mu igbo.
Olori awọn alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Ọmọọba Olumuyiwa Adejọbi, nigba to n sọrọ lori ikanni ayelujara ti Twitter, o sọ pe ki gbogbo ẹni to ba mọ ọkunrin ọhun fi to ileeṣẹ wọn leti.
Adejọbi sọ pe “Gbogbo wa la le ri eyi, Bawo lo ṣe ri ọmọ naa? Ṣe ọmọ rẹ ni? Abi ọmọ ẹgbọn abi ọmọ aburo? Eyikeyi ti yoo baa jẹ, awọn iya gbọdọ fi eyi kọgbọn, ẹ ma ṣe gbe awọn ọmọ yin le awọn ti ko yẹ lọwọ. Kii ṣe gbogbo eeyan lo le tọju ọmọ daadaa fun un yin. A n fẹ ẹkunrẹrẹ nipa ọmọkunrin yii.”
Fọnran naa ree
No comments:
Post a Comment