Ile ọdun ni Wasiu lọ, ni wọn ba ji ọkada rẹ gbe salọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, January 8, 2023

Ile ọdun ni Wasiu lọ, ni wọn ba ji ọkada rẹ gbe salọ


Kani kii ṣe ọla inu kan ti wọn sọ pe Wasiu Akanni n lo lati fi b'awọn eeyan ṣe ni, o ṣee ṣe ko ma pada ri ọkada rẹ t'awọn adigunjale jigbe salọ lọsẹ to kọja yii gba pada.
 
Ileeṣẹ eleto aabo ipinlẹ Ogun ti a mọ si So-Safe la gbọ pe wọn ba Wasiu gba ọkada rẹ lọwọ awọn to jiigbe salọ.
 
AWIKONKO gbọ pe ile ọdun ni Wasiu lọ niluu Ita-Ẹgbẹ to wa nijọba ibilẹ Ipokia lọjọ kọkanlelọgbọn pẹlu ọkada Bajaj rẹ, to si gbe ọkada naa sẹgbẹ ile baba rẹ, toun si wa ninu ile.

Ko ju bii iṣẹju meloo kan lọ ti Wasiu fi jade sita pada, to si ṣakiyesi pe ọkada oun ko si nibi toun gbe e si, wọn ti jiigbe salọ. Ere ni wọn lo kọkọ pe e, ti wọn si ni ṣe lo pe awọn to lero wi pe wọn le gbeọkada naa lai sọ fun un.

Gbogbo awọn ti Wasiu pe patapata ni wọn sọ pe awọn ko ri ọkada rẹ. Bayii ni wọn ṣe bẹrẹ sii wa a, ko to di pe wọn lọ fi to awọn oṣiṣẹ aabo So-Safe Corps leti.
 
A gbọ pe awọn oṣiṣẹ aabo naa lati ẹkun Idiroko ti wọn n ṣiṣẹ ofintoto kaakiri ni nnkan bi aago meje ku iṣẹju mẹẹdogun irọlẹ, ọjọ kẹrin, oṣu yii ni wọn kofiri awọn meji kan ti wọn n ja si ọkada lọwọ. Loju ẹsẹ ni wọn ti sunmọ wọn lati mọ ohun to n ṣẹlẹ.
 
Bi wọn ṣe de ọdọ wọn lawọn mejeeji bẹrẹ sii sọ kobokobo wi pe awọn lawọn ni ọkada, ti wọn ko si le ko awọn iwe ọkada naa suilẹ, gẹgẹ bi ẹri wi pe awọn ni wọn nii.
 

Adeyanju Daniel, ẹni ọdun mejilelọgbọn to n gbe nile Baba Uwuku to wa ni Oko Cashew, Ihunbọ ati Emmadu Mathew, ọmọ ọdun mẹrindinlọgbọn toun wa lati Izini, Iponle, Isakete, orileede olominra Bẹninlawọn mejeeji naa.
 
Gbogbo ibeere ti wọn beere lọwọ wọn la gbọ pe wọn ko le fidi ẹ mulẹ, eyi to jẹ ki aṣiri tu pe niṣe ni wọn ji ọkada naa ti nọmba idanimọ rẹ jẹ TRE 742 UX gbe.
 
Nibi ti wọn ti n ṣe iwadii laṣiri ti tu pe Wasiu lorukọ ẹni to ni ọkada naa ti wọn jigbe lagbegbe Ita-Ẹgbẹ.

Ọga agba fun ileeṣẹ eleto aabo ọhun, Sọji Ganzallo ti paṣẹ pe ki wọn lọ fa awọn mejeeji le ileeṣẹ ọlọpaa, ẹkun Idiroko lọwọ lati tẹsiwaju iwadii wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI