Wọn ti yọ ọga ọlọpaa Ibara to jẹ ki afurasi to lọwọ ninu iku tọkọ-tiyawo l'Abẹokuta salọ n'ipo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, January 8, 2023

Wọn ti yọ ọga ọlọpaa Ibara to jẹ ki afurasi to lọwọ ninu iku tọkọ-tiyawo l'Abẹokuta salọ n'ipo


Iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ ti sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti yọ ọga ọlọpaa ẹkun Ibara, CSP Bernard Ediagbonya n'ipo, wọn si lo ti lọ fi ara rẹ silẹ fun iwadii ni olu ileeṣẹ wọn to wa ni Eleweran.
 
Ediagbonya la gbọ pe o ṣee ṣe ko mọ nipa bi afurasi t'ọwọ tẹ naa ṣe na papa bora.
 
AWIKONKO gbọ pe latigba ti ọwọ ti tẹ Lekan Adekanbi, ẹnikan ṣoṣo ti wọn sọ pe wọn fura si lati lọwọ ninu iku Ọgbẹni Kẹhinde Fatinoye ati iyawo rẹ, Arabinrin Olubukọnla Fatinoye.
 
Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ko tii dahun ibeere lati ọdọ awọn akọroyin sibẹ, ohun ti a gbọ ni pe Ediagbonya ti wa ni Eleweran, nibi ti wọn ti n fọrọ wa a lẹnu wo nipa idi ti ko ṣe fi ṣẹkẹsẹkẹ sọwọ afurasi naa lọsibitu.
 
Siwaju sii la gbọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti paṣẹ pe ki ẹnikan to tun jẹ ọga ọlọpaa gba ipo Ediagbonya loju ẹsẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI