Iṣẹ agbẹ la wa ṣe ni Naijiria - Awọn bororo Niger jẹwọ f'awọn ẹṣọ aabo l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 5, 2023

Iṣẹ agbẹ la wa ṣe ni Naijiria - Awọn bororo Niger jẹwọ f'awọn ẹṣọ aabo l'Ogun


Ọwọ ileeṣẹ eleto aabo ipinlẹ Ogun, Ogun State Community, Social Orientation and Safety Corps, So-Safe ti tẹ awọn ajoji mẹwaa kan ti wọn sọ pe orileede Niger ni wọn ti wọ Naijiria lọna aitọ.

Gẹgẹ agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Ọgbẹni Mọruf Yusuf ṣe ṣalaye fun AWIKONKO l’Ọjọru, Wẹsidee, ọsẹ yii, o sọ pe ilu Ihunbọ to wa n’ijọba ibilẹ Ipokia lọwọ ti tẹ awọn mẹwaa naa lọjọ kinni, oṣu kinni, ọdun 2023.

Yusuf ṣalaye pe ọkunrin ni gbogbo awọn mẹwaa tọwọ tẹ, to si ni ọna aitọ ni wọn gba wọ orileede Naijiria. Ati pe inu igbo kijikiji ni wọn gba wọle

Yusuf Mohammed, Nura Abdullahi, Afisu Dairu, Gafar Abdulmumeen, Abubakar Subair, Amisu Nasiru, Illiasu Yahyah, Ibrahim Audu, Suraju Ibrahim ati Mohammed Garuba ti wọon loun ni olori wọn l’awọn mẹwẹẹwa tọwọ tẹ naa.


O ni awọn oṣiṣẹ wọn lati ẹkun Idiroko lo rọwọ to wọn lakoko ti wọn n rin gberegbere kaakiri inu igbo, ti wọn si fura si irinsẹ wọn, eyi lo jẹ ki wọn lọ koju wọn lati beere ibi ti wọpn n lọ.

Bakan naa lo fi ye wa pe nigba ti wọn n beere ọrọ lọwọ wọn, ohun ti wọn ṣalaye ni pe iṣẹ agbẹ lo gbe wọn de orileede Naijiria, ati pe agbegbe Ita-Ẹgbẹ l’awọn pinnu lati ṣiṣẹ agbẹ wọn.

Ni bayii, ọga agba fun ileeṣẹ eleto aabo So-Safe ọhun, Ọmọwe Olusọji Ganzallo ti paṣẹ pe ki wọn ko awọn mẹwẹẹwa naa lọ si ileeṣẹ to n ri sọrọ eto irinna, iyẹn Nigeria Immigration Services fun iwadii kikun nipa wọn, lati le gbe igbesẹ to tọ labẹ ofin.

Ganzallo wa rawọ ẹbẹ s’awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Ogun lati ma ṣe maa gboju fo awọn ajoji to ba n kọja lagbegbe wọn da, nitori pe ohun to ṣe pataki ni lati maa wa ni ikiyesara, ki eto aabo le tubọ kẹsẹjari.

O ni bi wọn ba n kofiri ajoji lagbegbe wọn, ki wọn tete maa fi to ileeṣẹ eleto aabo bii ti wọn leti lati gbe igbesẹ to yẹ lasiko.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI