Dapọ Abiọdun bura fun akọwe agba tuntun marun-un, oludamọran pataki kan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 5, 2023

Dapọ Abiọdun bura fun akọwe agba tuntun marun-un, oludamọran pataki kan


Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun ti bura fawọn akọwe agba tuntun marun-un ati oludamọran pataki kan ti yoo tẹsiwaju nibi ti awọn to ti fẹyinti ti bẹrẹ.

Ọjọru, Wẹsidee, ọsẹ yii ni Gomina Abiọdun bura fawọn eeyan naa ni ọfisi rẹ to wa ni Oke-Mọsan niluu Abẹokuta.

Nibẹ ni Abiọdun ti gba awọn to ṣẹṣẹ yan naa lamọran lati tẹra mọ iṣẹ ti wọn gbe le wọn lọwọ, ki wọn si rii daju pe wọn n fi ifẹ lo.

O ni ki wọn gbe imọ igbalode ti yoo ba asiko yii mu kalẹ lati mu iṣẹ isin ijọba ati ipinlẹ naa tẹsiwaju.
 
Oludamọran pataki naa ni Arabinrin Ayọtunde Ọlasunmbọ Lawal.

Awọn akọwe agba tuntun naa ni: Onimọ-ẹrọ Ṣakirudeen Ayinde; Ọgbẹni Towolabi Adeṣina Muftau; Ọgbẹni Hameed Morakinyọ; Ọmọwe Ẹlẹmide Ọlayinka Nikẹ ati Ọgbẹni Augustus Adesọji.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI