Mi o kii binu si awọn to ba dalẹ, ṣugbọn... - Tinubu tu aṣiri nla - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, January 31, 2023

Mi o kii binu si awọn to ba dalẹ, ṣugbọn... - Tinubu tu aṣiri nla


Oludije s'ipo aarẹ orileede Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu ti sọ pe oun kii binu si awọn to ba n dalẹ oun, bi ko ṣe pe niṣe loun yoo kan pa wọn ti ni.
 
O ni bi awọn eeyan ba dalẹ oun, o maa n fun oun ni ọkan akikanju lati tẹra mọ iṣẹ ni, koun le ṣe aṣeyori, dipo koun maa binu si ẹni naa, to si loun kii rii ro rara.

Aṣiwaju Tinubu lo sọ eyi di mimọ nibi ipade inu gbọngan, iyẹ Town Hall Meeting to ṣe pẹlu awọn agbaagba ati alẹnulọrọ lẹgbẹ oṣelu APC niluu Benin, ipinlẹ Ẹdo l'ọjọ Aiku, Sannde to kọja yii.
 
Lara awọn to tun wa nibi ipade naa lawọn ẹgbẹ oniṣẹ ọwọ, ati awọn ẹgbẹ oniṣowo kaakiri ipinlẹ naa, nibi to ti gba wọn lamọran wi pe ki wọn dide lati ṣiṣẹ ti yoo gbe oun de ipo aarẹ lọdun 2023 ti a wa yii.
 
Ninu ọrọ rẹ, Tinubu sọ pe
“Ijakulẹ jẹ ohun amuṣagbara fun mi. Ẹ ko le ja mi kulẹ, maa ṣiṣẹ takuntakun ni. Bi ẹ ba dalẹ mi, mi o ni binu, maa kan pa ẹ ti ni, mi o si ni tiẹ ro.

“Idi ni pe iwọ kọ ni Ọlọrun mi, iwọ si kọ lo da mi saye. Iya mi lo kọ mi pe bi ọkan rẹ ba bajẹ, maa ba ẹ pin nibẹ. Bi inu rẹ ba n dun, maa ba ẹ yọ pẹlu. Bi o ba toṣi, maa pin lara diẹ ti mo ni pẹlu ẹ.”

Nigba to n fi ọkan awọn ara ipinlẹ Ẹdo balẹ, o sọ pe orileede yii ni awọn ohun amuṣọrọ to le gbe e duro, paapaa nipa afẹfẹ gaasi to wa n'ipinlẹ naa, ti yoo si jẹ ki Naijiria dagbasoke.

O rọ awọn eeyan naa lati dide, ki wọn si duro ṣinṣin lati gba ipinlẹ naa kuro lọwọ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, ki wọn si daa pada fun APC.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI