Atiku ko mọ irọ to tun le pa mọ, o kan n parọ lori irọ ni - Tinubu tun kọlu Atiku - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, January 31, 2023

Atiku ko mọ irọ to tun le pa mọ, o kan n parọ lori irọ ni - Tinubu tun kọlu Atiku


Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu to jẹ oludije s'ipo aarẹ orileede Naijiria ninu eto idibo ọdun 2023 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC tun ti kọlu alatako rẹ, iyẹn Alaaji Atiku Abubakar toun jade du ipo aarẹ kan naa labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP.

Tinubu sọ pe opurọ aye ati ọrun ni Atiku, ti ko si mọ iru irọ tun le pa mọ lakoko oṣelu to wa nita yii f'awọn ọmọ Naijiria, eyi to mu ko maa parọ lori irọ lati wa ojurere awọn eeyan.

O ni ko si anfaani kankan ti Atiku fẹẹ ṣe f'awọn araalu, bi ko ṣe pe ko tun wa a jẹ Naijiria run gẹgẹ bi iṣe rẹ.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe 
“Ṣe ẹ ri ẹgbẹ PDP, wọn ti tuka, wọn ko mọ ọna mọ. Atiku ko mọ bo ṣe le parọ mọ yatọ si ko maa parọ lori irọ. Atiku ko le da iṣẹ gidi kan silẹ ni Naijiria. Nigba ti wọn fẹẹ sọ ileeṣẹ Aluminium Smelter Company to wa ni Ikot Abasi ati NITEL di aladani, ẹmi n dunadura pẹlu awọn China lori Free Trade Zone. Mo tun dunadura lori papakọ ori omi ti Lẹkki, iyẹn Lekki Deep Seaport lorilẹẹde Singapore, o si wa jẹ eyi to jinna ju nilẹ Adulawọ, iyẹn West Africa. Awọn ara Edo jafafa gidi, ẹ si le ṣiṣẹ naa.
“A fọkan balẹ lori mi n'ijọba apapọ. Maa jẹ aarẹ yin to n gbọran. Ẹ dibo fun mi. Aṣeyọri wa nibi yii. Nigba ti ẹ ba gbe iwe silẹ ninu patako, ẹ sọ pe fun idaṣẹsilẹ ni. Maa pese iṣẹ fun un yin nitori mọ mọ pe ẹ kii ṣe ọlẹ.”
“Awọn ti wọn ko le fun Naijiria ni agbara sọ pe awọn tun fẹẹ pada wa. Laaarin ọdun mẹjọ pere, APC da ọkọ oju irin pada. A maa da awọn ileeṣẹ ifọpo pada, a ma si ma maa pese epo fun un yin. Wọn le bu Buhari lati aarọ di alẹ, ko gbọ eebu wọn.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI