Nibi ti Adebọwale ti fẹẹ ji ọkada gbe lọwọ Amọtẹkun ti tẹẹ l'Oṣogbo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, January 28, 2023

Nibi ti Adebọwale ti fẹẹ ji ọkada gbe lọwọ Amọtẹkun ti tẹẹ l'Oṣogbo


Ṣikun bayii lọwọ ẹṣọ aabo Amọtẹkun tẹ gendekunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Adebọwale, nibi to ti fẹẹ ji ọkada ọlọkada gbe niluu Oṣogbo, to si n bẹbẹ fun ẹyinju aanu.
 
Adugbo ti wọn pe ni Aratumi, eyi to wa lagbegbe Kelebe niluu Oṣogbo, ipinlẹ Ọṣun ni wọn sọ pe Adebọwale, ọmọ ọdun marundinlọgbọn naa ti ji ọkada ọhun gbe.
 
Nigba to n sọrọ, ọga agba pata f'awọn Amọtẹkun nipinlẹ naa, Ọgagun Bashir Adewinmbi ṣalaye pe akoko ti awọn oṣiṣẹ wọn n ṣe ofintoto kaakiri lọwọ wọn tẹ Adebọwale nibi to ti n gbiyanju lati ji ọkada gbe ni nnkan bi aago kan ooru, Ọjọru, Wẹsidee to kọja yii.
 
Adewinmbi sọ pe awọn ko fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ aabo ẹmi ati dukia awọn araalu, idi ree ti wọn fi n ṣiṣẹ loore koore lai wo ti oju ọjọ.
 
O tẹsiwaju pe ko si ibi ti awọn amookunṣeka wa, tọwọ palaba wọn ko nii segi, nitori pe iṣẹ tawọn gba niyẹn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI