Nko jẹbi pẹlu alaye, ẹ dariji mi - Baba to n fi ojoojumọ ba ọmọ rẹ, ọmọ ọdun mẹtala laṣepọ ṣalaye fun ile-ẹjọ l'EKoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, January 24, 2023

Nko jẹbi pẹlu alaye, ẹ dariji mi - Baba to n fi ojoojumọ ba ọmọ rẹ, ọmọ ọdun mẹtala laṣepọ ṣalaye fun ile-ẹjọ l'EKoo


Ika abamọ ni baale ile, ẹni ọdun marundinlogoji kan, Temitayọ Bamiro mu sẹnu niwaju adajọ uile ẹjọ Majisireeti to wa lagbegbe Ọjọọ niluu Eko lọjọ Aje, Mọnde to kọja yii.
 
'Ki ni mo ṣe eyi fun', lọrọ to n jade lọkan Bamiro, ẹni ti aṣiri rẹ tu wi pe o fipa ba ọmọ rẹ, ọmọ ọdun mẹtala laṣepọ, koda, wọn loun lo tun ja ibale ọmọ naa.
 
Agbefọba Simon Uche to wọ Bamiro lọ siwaju adajọ ṣalaye pe ọjọ keje, o'su kinni, ọdun ti a wa yii ni Bamiro ṣe ẹṣẹ ẹsun ti wọn fi kan an lagbegbe Iba New Site, Ọjọọ, ipinlẹ Eko.
 
O ni pẹlu ipa ni Bamiro fi ja ibale ọmọ ọhun, to si tun n ko ibasun fun un karakarak, ko to di pe ọwọ palba rẹ segi.
 
Uche ni ẹsun naa tako iwe ofin ọdaran tipinlẹ Eko, leyi to si gbọdọ jiya ẹṣẹ rẹ labẹ ofin lẹkunrẹrẹ, ṣugbọn Bamiro loun ko jẹbo pẹlu alaye.
 
Ninu ọrọ Onidajọ L.J.K. Layẹni, o tare ọrọ naa sọdọ ajọ Directorate of Public Prosecution (DPP) fun igbanimọran labẹ ofin, o si wa sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kejilelogun, oṣu keji, ọdun 2023.
 
Bakan naa lo paṣẹ pe ni gbogbo asiko yii, ki Bamiro ṣi lọ maa gbatẹgun alaafia l'ọgba ẹwọn to wa ni Badagry.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI