O ma ṣe o! Ẹ wa gbọ aṣiri iku to pa Magaji, gbajumọ Ọnarebu ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, January 9, 2023

O ma ṣe o! Ẹ wa gbọ aṣiri iku to pa Magaji, gbajumọ Ọnarebu ni Kwara


Inu ibanujẹ nla l'awọn ẹbi, ọrẹ, to fi mọ ololufẹ ati alatilẹyin gbajugbaja Ọnarebu kan niluu Ilọrin wa titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, nitori bi Ọnarebu naa ṣe gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra.
 
Aarọ oni, ọjọ Aje, Mọnde ni iroyin fi to wa leti pe Ọnarebu naa, Ọnarebu Ọlawọyin Abubakar Magaji jade laye lẹni ọdun mẹtadinlọgọta.

Ọnarebu Magaji ni olori awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin to pọ ju nipinlẹ naa. Oun lo si n ṣoju agbegbe Aarin gbungbun Ilọrin nile igbimọ aṣofin naa ko to jade laye.

Aisan rampẹ kan ni wọn loo kọlu Ọnarebu Magaji, ti wọn si lawọn eeyan ẹ sare gbe e digbadigba lọ si ọsibitu, ṣugbọn to pada jẹ pe ibẹ ni wọn ti kede oku rẹ fun wọn.

B'awọn kan ṣe n gbera ṣanlẹ, bẹẹ l'awọn miran n wa ẹkun mu, nitori ti wọn sọ pe ojiji ni iroyin iku naa ba wọn.


Ọkan lara awọn ọnrebu nile igbimọ aṣofin, Ọnarebu Awolọla Ọlamide Ayọkunle to alaga igbimọ to n ri sọrọ awọn ọdọ, ere idaraya ati irin ajo afẹ lo kede iroyin iku Ọnarebu Magaji ninu atẹjade to gbe sita niluu Ilọrin.
 
Aago mẹrin, irọlẹ onii la gbọ pe wọn yoo sinku rẹ lagboole Magajin Geri to wa lagbegbe Surulere niluu Ilọrin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI