Ijọba Yobe kede isinmi ọjọ meji f'awọn oṣiṣẹ nitori Buhari to fẹẹ lọ ki wọn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, January 9, 2023

Ijọba Yobe kede isinmi ọjọ meji f'awọn oṣiṣẹ nitori Buhari to fẹẹ lọ ki wọn


Gomina ipinlẹ Yobe, Mai Mala Buni ti kede isinmi ọjọ meji fun gbogbo awọn oṣiṣẹ ipinlẹ naa patapata.
 
Ohun ti a gbọ ni pe Aarẹ Muhammadu Buhari lo fẹẹ lọ s'ipinlẹ naa lati lọ ṣi awọn akanṣe iṣẹ idagbasoke ti ijọba ipinlẹ naa ṣe.
 
Alaaji Garba Bilal to jẹ olori awọn oṣiṣẹ ipinlẹ Yobe lo gbe iroyin naa sita lọjọ Aiku, Sannde to kọja yii, to si ni Aarẹ Buhari le fi raaye lati ṣi gbogbo awọn akanṣe iṣẹ naa lo fa a.
 
Lara awọn akanṣe iṣẹ ti Aarẹ Buhari fẹẹ ṣi ni papakọ ofurufu akẹru, iyẹn Cargo Airport, Ọja igbalode nla, aragbayamuyamu ọsibitu at'awọn ibudo eto ilera.
 
Ọjọ kẹsan si ọjọ kẹwaa ni isinmi naa yoo jẹ, ti wọn yoo si pada si ẹnu iṣẹ wọn l'ọjọ kọkanla tii ṣe Wẹsidee.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI