O ma ṣe o! Ejo ṣan akẹkọọ ile ẹkọ girama pa ninu kilaasi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, January 17, 2023

O ma ṣe o! Ejo ṣan akẹkọọ ile ẹkọ girama pa ninu kilaasi


Bi ẹlẹkun ṣe n bu sẹkun, bẹẹ lawọn miran n gbe ara wọn ṣanlẹ nibi ti wọn ti sinku ọmọdebinrin akẹkọọ ile-ẹkọ girama kan, Melody Chiputura, ẹni ti wọn sọ pe ejo afaayafa ṣan pa ninu kilaasi.
 
Ipele kẹfa ti a mọ si 'Form 6' la gbọ pe Melody wa nile ẹkọ girama ti Rushinga to wa ni Zimbabwe’s Mashonaland Central Province.
 
A gbọ pe ibi ere idaraya ti awọn akẹkọọ lọ ṣe ni Melody, ọmọ ọdun mẹtadinlogun ọhun ti kuro lọsan ọjọ naa, ko to wọ kilaasi.
 
Ko pẹ to wọ kilaasi ni wọn sọ pe ejo afaayafa naa ṣan ni ẹsẹ, to si pariwo. Loju ẹsẹ la gbọ pe wọn ti sare gbe e digbadigba lọ si ọsibitu lati tọju ẹ.
 
Wọn ni ọsibitu naa lo pada dakẹ si lẹyin ọgbọn iṣẹju ti ejo ọhun ge e jẹ. Bo ṣe ku ni wọn ti lọ sinku rẹ, nitori pe ibanujẹ nla lo jẹ.
 
Baba Melody, Ọgbẹni Joseph Chiputura, nigba to n banujẹ sọrọ lori iku ọmọ rẹ, o ni ọgbẹ ọkan nla lo jẹ foun, nitori pe ẹyinloju oun ni Melody jẹ, to si ni gbogbo nnkan to ba n fẹ loun maa n fun un.
 
O lo ya oun lẹnu pe ejo le ṣan ọmọ oun, ti yoo si wa ku lẹyin ọgbọn iṣẹju si asiko naa. Bẹẹ lo sọ pe iṣẹlẹ ọhun kii ṣoju lasan, nitori pe o ṣoro lati gbagbọ.
 
“Lẹyin iṣẹju mẹwaa ti ejo ṣan an ni wọn pe mi lori foonu lati fi to mi leti. Nigba ti a maa de ile iwosan naa, ẹpa ko boro mọ. Eyi sọro pupọ lati gbagbọ, o si dun mi gidi. Ko ye mi bi ejo yoo ṣe wọ inu kilaasi, ko si jẹ pe ọmọ mi lo maa ṣan jẹ.
 
“Ọmọ mi ni afojusun ọjọ iwaju gidi, nitori pe o ja fafa, o si fẹran ko maa lọ sileewe. O ni ireti nla to jẹ ki eto ẹkọ wuu pupọ. Eyi lo n jẹ ka maa pese gbogbo nnkan to ba n fẹ fun un. Ẹkọ nipa itan, iwoye ati ẹsin (History, Psychology and Religious Studies) lo n kọ nileewe, ala rere rẹ si ni lati di amoye nla (psychologist.)”
 
Oga ileewe naa, Ọgbẹni Christopher Mureng ninu ọrọ tiẹ naa sọ pe;
“Ọjọbọ, Tọsidee niṣẹlẹ ọhun waye, nigba ti gbogbo awọn akẹkọọ lọ fun eto ere idaraya, gẹgẹ bo ṣe wa ninu ilana eto ẹkọ wa.
“Nnkan bi aago mẹrin ku iṣẹju mẹwaa ni gbogbo aọn akẹkọọ pada si kilaasi lọjọ, lati lọ palẹmọ fun ile lilọ.
“O jokoo lori aga rẹ, aga kẹta si ogiri lo n jokoo, awọn akẹgbẹ rẹ meji lo si n jokoo niwaju ẹ. Lojiji lo pariwo jade, to si sọ pe nnkan ti ṣan oun.
“Awọn akẹkọọ naa ṣakiyesi ejo yii, eyi to mu ki onikaluku bẹrẹ sii sa asala fun ẹmi ara rẹ. Bawọn kan ṣe sare jade lawọn miran gba oju ferese fo jade. Lara awọn akẹkọọ-kunrin ni wọn gbe Melody jade sita, ti wọon si n pariwo fun iranlọwọ.
“Ogun iṣẹju si asiko naa lawọn obi rẹ de pẹlu awọn egboogi ibilẹ kan lati fun un lo.
“Igba naa la kan si awọn oṣiṣẹ ọsibitu Chimhanda, ti dọkita naa si gba wa lamọran lati gbe Melody ati ejo naa ti wọn ti pa wa sọdọ oun.
“Oju ọna lo ti dakẹ. Ọkan wa ko tii balẹ nitori pe ibanujẹ lo jẹ fun wa. Ko ye wa bi ejo ṣe wọnu kilaasi, a ko si mọ ibi to ti wa.
“Ibi ti kilaasi naa wa jinna si ibi ti a le sọ pe ejo le wa lati maa ṣere kaakiri
.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI