O ti n doju ẹ bayii: Wọn tun ji igbekeji alaga kansu gbe - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, January 17, 2023

O ti n doju ẹ bayii: Wọn tun ji igbekeji alaga kansu gbe


Awọn agbẹbọ la tun gbọ pe wọn ti ji igbekeji alaga kansu n'ijọba ibilẹ Musawa, ipinlẹ Katsina,
Aminu Umar Kira gbe.
 
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe nnkan bi aago kan oru, ọjọ Aje, Mọnde oni, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kinni, ọdun yii ni wọn ji Kira ati ẹnikan ti wọn pe orukọ ẹ ni Isah Paiki gbe.

Abule Kira to n gbe ni wọọdu Jimkamshi ni wọn ti ji awọn mejeeji gbe.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, SP Gambo Isah, nigba to n f'idi iṣẹlẹ ọhun mulẹ sọ pe otitọ ni, ati pe awọn ti ri Paiki gba jade kuro lọwọ wọn, to si ni igbesẹ ṣi n lọ lọwọ lati ri igbakeji laga kansu naa gba jade.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI