O tan! Oludije lẹgbẹ oṣelu Labour fẹgbẹ silẹ ni Kwara, lo ba lọ darapọ APC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, January 8, 2023

O tan! Oludije lẹgbẹ oṣelu Labour fẹgbẹ silẹ ni Kwara, lo ba lọ darapọ APC


Ọkan pataki lara awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Labour nipinlẹ Kwara, Ọnarebu Abdulkareem Ismail ni iroyin fi to wa leti wi pe o ti fẹgbẹ naa silẹ, o si ti ba ẹgbẹ miran lọ.
 
AWIKONKO gbọ pe Ọnarebu Ismail to jẹ oludije sipo ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour lati ẹkun Ilọrin East lo kede sita wi pe oun ko le tẹsiwaju mọ ninu ẹgbẹ ọhun.
 
O ni ẹgbẹ oun ko ri ọjọ iwaju rere ninu ẹgbẹ oṣelu Labour mọ, bo tilẹ jẹ pe ibẹ loun ti fẹẹ jade du ipo, ṣugbọn to ni ẹgbẹ kan ṣoṣo toun ri ọjọ ọla daadaa fun ni APC, iyẹn All Progressives Congress.
 
Siwaju sii ni Ismail jẹ ko di mimọ pe lara awọn idi pataki toun fi darpọmọ APC ni aṣeyọri ti Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ṣe, ati pe o tun ni ipinnu rere f'awọn araalu, to si lo di dandan koun ṣatilẹyin saa keji fun, ki ilọsiwaju le tubọ maa de ba Kwara.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI